40 Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ṣe sọ láti ẹnu Mósè. Èyí yóò jẹ́ ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ẹlòmíràn yàtọ̀ sí irú ọmọ Árónì kò gbọdọ̀ jó tùràrí níwájú Olúwa, ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò dàbí Kórà àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.
41 Ní ọjọ́ kejì gbogbo ìjọ ènìyàn kùn sí Mósè àti Árónì pé, “Ẹ ti pa àwọn ènìyàn Olúwa.”
42 Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn péjọ lòdì sí Mósè àti Árónì, níwájú àgọ́ ìpàdé, lójijì ni ìkúùkù bolẹ̀, ògo Olúwa sì fara hàn.
43 Nígbà náà ni Mósè àti Árónì lọ ṣíwájú àgọ́ ìpàdé,
44 Olúwa sì sọ fún Mósè pé,
45 “Yàgò kúrò láàrin ìjọ ènìyàn yìí, kí ń ba le run wọ́n ní ìṣẹ́jú kan.” Wọ́n sì dojú bolẹ̀.
46 Mósè sì sọ fún Árónì pé, “Mú àwo tùràrí, kí o fi iná sí i lórí pẹpẹ, fi tùràrí sínú rẹ̀, kí o sì tètè mu lọ sí àárin ìjọ ènìyàn láti ṣètùtù fún wọn nítorí pé ìbínú Olúwa ti jáde, àjàkálẹ̀-àrùn sì ti bẹ̀rẹ̀.”