10 Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà mẹ́ta; a sì tún fa gbogbo rẹ̀ sókè ọ̀run.
11 “Sì wò ó, lójúkan náà ọkùnrin mẹ́ta dúró níwájú ilé ti a gbé wà, ti a rán láti Kesaríà sí mi.
12 Ẹ̀mí sì wí fún mi pé, kí èmi bá wọn lọ, ki èmi má ṣe kọminú ohunkóhun. Àwọn arákùnrin mẹ́fà wọ̀nyí sì bá mi lọ, a sì wọ ilé ọkùnrin náà:
13 Ó sì sọ fún wa bí òun ti rí ańgẹ́lì kan tí ó dúró ní ilé rẹ̀, tí ó sì wí pé, ‘Ránṣẹ́ lọ sí Jópà, kí ó sì pe Símónì tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ Pétérù;
14 Ẹni tí yóò sọ ọ̀rọ̀ fún ọ, nípa èyí tí a ó fi gba ìwọ àti gbogbo ilé rẹ là.’
15 “Bí mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sì sọ, Ẹ̀mi Mímọ́ sì bà lé wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti bà lé wa ni àtètèkọ́ṣe.
16 Nígbà náà ni mo rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí pé, ‘Jòhánù fi omi bamitíìsì nítóòtọ́; ṣùgbọ́n a ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì yín.’