17 Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.”
18 Díẹ̀ ni ó kù kí wọn má le fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ènìyàn dúró, kí wọn má ṣe rúbọ bọ wọ́n.
19 Àwọn Júù kan sì ti Áńtíókù àti Ìkóníónì wá, nígbà tí wọ́n yí àwọn ènìyàn lọ́kan padà, wọ́n sì sọ Pọ́ọ̀lù ní òkúta, wọ́n wọ́ ọ kúrò sí ẹ̀yin odi ìlú náà, wọn ṣèbí ó kú.
20 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn dúró ti i yíká, ó dìde ó sì padà wọ inú ìlú náà lọ. Ní ọjọ́ kejì ó bá Bánábà lọ sí Dábè.
21 Nígbà tí wọ́n sì ti wàásù ìyìn rere fún ìlú náà, tí wọ́n sì ni ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀, wọn padà lọ sí Lísírà, àti Ikóníónì, àti Áńtíókù,
22 wọn sì ń mú àwọn ẹ̀yìn lọ́kàn le, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú láti dúró ní ìgbàgbọ́, àti pé nínú ìpọ̀njú púpọ̀, ni àwa ó fi wọ ìjọba Ọlọ́run.
23 Nígbà tí wọ́n sì ti yan àwọn alàgbà fún olúkúlùkù ìjọ, tí wọn sì ti fi àwẹ̀ gbàdúrà, wọn fi à wọ́n lé ẹni gbàgbọ́ Olúwa lọ́wọ́.