17 Ìròyìn yìí sì di mímọ̀ fún gbogbo àwọn Júù àti àwọn ará Gíríkì pẹ̀lú tí ó ṣe àtìpó ní Éfésù; ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn, a sì gbé orúkọ Jésù Olúwa ga.
18 Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ sì wá, wọ́n jẹ́wọ́, wọ́n sì fi iṣẹ́ wọn hàn.
19 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí ń se alálùpàyídà ni ó kó ìwé wọn jọ, wọ́n dáná sun wọ́n lójú gbogbo ènìyàn: wọ́n sì sirò iye wọn, wọ́n sì rí i, ó jẹ́ ẹgbàámẹ́ẹ̀dọ́gbọ́n ìwọ̀n fàdákà.
20 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa gbérú tí o sí gbilẹ̀ si í gidigidi.
21 Ǹjẹ́ bí nǹkan wọ̀nyí tí parí tan, Pọ́ọ̀lù pínnu nínú ẹ̀mí rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kọjá ní Makedóníà àti Ákáyà, òun ó lọ sí Jerúsálémù, ó wí pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo bá dé ibẹ̀, èmi kò lè ṣàì má dé Róòmù pẹ̀lú.”
22 Nígbà tí ó sì tí rán méjì nínú àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un lọ ṣí Makedóníà, Tímótíù àti Érásítù, òun tìkararẹ̀ dúró díẹ̀ ní ilẹ̀ Éṣíà.
23 Ní àkókò náà ìrúkèrúdò díẹ̀ kan wà nítorí ọ̀nà náà.