10 Heṣekáyà ni baba Mánásè;Mánásè ni baba Ámónì;Ámónì ni baba Jósáyà;
11 Jósáyà sì ni baba Jékónáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Bábílónì.
12 Lẹ́yìn ìkólọ sí Bábílónì:Jékónáyà ni baba Selítílì;Selítílì ni baba Sérúbábélì;
13 Sèrérúbábélì ni baba Ábíúdì;Ábíúdì ni baba Élíákímù;Élíákímù ni baba Ásórì;
14 Ásórì ni baba Sádókù;Sádókù ni baba Ákímù;Ákímù ni baba Élíúdì;
15 Élíúdì ni baba Élíásárì;Élíásárì ni baba Mátítánì;Mátítánì ni baba Jákọ́bù;
16 Jákọ́bù ni baba Jósẹ́fù, ẹni tí ń ṣe ọkọ Màríà, ìyá Jésù, ẹni tí í ṣe Kírísítì.