Mátíù 8 BMY

Ọkùnrin Adẹ́tẹ̀

1 Nígbà tí ó ti orí òkè sọ̀ kalẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

2 Sì wò ó, adẹ́tẹ̀ kan wà, ó wá ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ ó wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mi di mímọ́.”

3 Jésù si nà ọwọ́ rẹ̀, ó fi bà á, ó wí pé, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́”. Lójú kan náà, ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sì mọ́!

4 Jésù sì wí fún pé, “Wò ó, má ṣe sọ fún ẹnì kan. Ṣùgbọ́n máa ba ọ̀nà rẹ̀ lọ, fi ara rẹ̀ hàn fún àlúfáà, kí o sì san ẹ̀bùn tí Mósè pa laṣẹ ní ẹ̀rí fún wọn.”

Ìgbàgbọ́ Balógun Ọ̀rún

5 Nígbà tí Jésù sì wọ̀ Kápánámù, balógun ọ̀rún kan tọ̀ ọ́ wá, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́.

6 O sì wí pé, “Olúwa, ọmọ-ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ àrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá.”

7 Jésù sì wí fún un pé, “Èmi ń bọ̀ wá mú un láradá.”

8 Balógun ọ̀rún náà dahùn, ó wí pé, “Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ mi láradá.

9 Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹnì kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ-ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”

10 Nígbà tí Jésù gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Ísírẹ́lì tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí.

11 Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìha ìlà-oòrùn àti ìhà iwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Ábúráhámù àti Ísáákì àti Jákọ́bù jẹun ní ìjọba ọ̀run.

12 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọba ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.”

13 Nítorí náà Jésù sì wí fún balógun ọ̀run náà pé, “Máa lọ ilé, ohun tí ìwọ gbàgbọ́ ti rí bẹ́ẹ̀.” A sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ náà lára dá ní wákàtí kan náà.

Jésù Wo Ọ̀pọ̀ Aláìsàn Sàn

14 Nígbà tí Jésù sì dé ilé Pétérù, ìyá ìyàwó Pétérù dùbúlẹ̀ àìsàn ibà.

15 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù fi ọwọ́ kan ọwọ́ rẹ̀, ibà náà fi í sílẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì dìde ó ń ṣe ìrànṣẹ fún wọn.

16 Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde. A sì mú gbogbo àwọn olókùnrùn láradá.

17 Kí èyí tí a ti sọ láti ẹnu wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ pé:“Òun tikara rẹ̀ gbà àìlera wa,ó sì ń ru àrùn wa.”

Ohun tí ó gbà láti tẹ̀lé Jésù

18 Nígbà tí Jésù rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó yí i ká, ó pàṣẹ pé kí wọ́n sọdá sí òdìkejì adágún.

19 Olùkọ́ òfin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí fún un pé, “Olùkọ́, èmi ó má tọ̀ ọ́ lẹ́yìn níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

20 Jésù dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀lọ̀kọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”

21 Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú bàbá mi ná.”

22 Ṣùgbọ́n Jésù wí fún un pé, “Má a tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú kí ó máa sin òkú ara wọn.”

Jésù Dá Ìjì-líle Dúró

23 Nígbà náà ni ó bọ́ sínú ọkọ̀ ojú-omi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e.

24 Ní àìròtẹ́lẹ̀, ìjì-líle dìde lórí òkun tó bẹ́ẹ̀ tí rírú omi fi bò ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n Jésù ń sùn.

25 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn jí i, wọ́n wí pe, “Olúwa, ‘gbà wá,’ àwa yóò rì.”

26 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. È é se ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù?” Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú òkun náà wí. gbogbo rẹ̀ sì pa rọ́rọ́.

27 Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? kódà ìji-líle àti rírú omi òkun gbọ́ tirẹ̀?”

Ìwòsàn Ọkùnrin Ẹlẹ́mìí-Èṣù méjì

28 Nígbà ti ó sì dé àpa kejì ní ilẹ̀ àwọn ara Gádárénésì, àwọn ọkùnrin méjì ẹlẹ́mìí-èṣù ti inú ibojì wá pàdé rẹ̀. Wọn rorò gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò le kọjá ní ọ̀nà ibẹ̀.

29 Wọ́n kígbe lóhùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tàwa tìrẹ, Ìwọ Ọmọ Ọlọ́run? Ìwọ ha wá láti dá wa lóró ṣáájú ọjọ́ tí a yàn náà?”

30 Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá tí ń jẹ̀ ń bẹ ní ọ̀nà jíjìn díẹ̀ sí wọn

31 Àwọn ẹ̀mí-èsú náà bẹ̀ Jésù wí pé, “Bí ìwọ bá lé wa jáde, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ yìí.”

32 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ!” Nígbà tí wọn sì jáde, wọn lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà; sì wò ó, gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà sì rọ́ gììrì sọ̀ kalẹ̀ bèbè-odò bọ́ sínú òkun, wọ́n sì ṣègbé nínú omi.

33 Àwọn ẹni tí ń ṣọ wọn sì sá, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n lọ sí ìlú, wọ́n ròyìn ohun gbogbo, àti ohun tí a ṣe fún àwọn ẹlẹ́mìí-èṣù.

34 Nígbà náà ni gbogbo ará ìlú náà sì jáde wá í pàdé Jésù. Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́, kí ó lọ kúrò ní agbégbé wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28