Mátíù 3 BMY

Jòhánù onítẹ̀bọmi Tún Ọ̀nà náà ṣe

1 Ní ọjọ́ wọ̀n-un-nì, Jòhánù onítẹ̀bọmi wá, ó ń wàásù ní ihà Jùdíà.

2 Ó ń wí pé, “Ẹ ronú pìwàdà, nítorí ìjọba ọ̀run dé tán.”

3 Èyí ni ẹni náà ti wòlíì Àìsáyà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé:“Ohùn ẹnìkan ti ń kígbe ní ihà,‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,ẹ se ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”

4 Irun ràkúnmí ni a fi hun aṣọ Jòhánù, awọ ni ó sì fi di àmùrè ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.

5 Àwọn ènìyàn jáde lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Jerúsálémù àti gbogbo Jùdíà àti àwọn ènìyàn láti gbogbo ìhà Jọ́dánì.

6 Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó ṣe í ìtẹ̀bọmi fún wọn nínú odò Jọ́dánì ibi tí ó ti ń se.

7 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ àwọn Farisí àti Sadúsì tí wọ́n ń wá si ìtẹ̀bọmi, ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀! Ta ni ó kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ́ sá kúrò nínú ibínú Ọlọ́run tí ń bọ̀?

8 Ẹ so èso tí ó yẹ fún ìrònú-pìwàdà.

9 Kí ẹ má sì ṣe rò nínú ara yin pé, ‘Àwa ní Ábúráhámù ní baba.’ Èmi wí fún yín, Ọlọ́run lè mu àwọn ọmọ jáde láti inú àwọn òkúta wọ̀nyí wá fún Ábúráhámù.

10 Nísinsin yìí, a ti fi àáké lè gbòǹgbò igi, àti pé gbogbo igi tí kò bá so èso rere ni a óò gé lulẹ̀ ti a ó sì jù wọn sínú iná.

11 “Èmi fi omi bamitíìsì yín fún ìrónúpìwàdà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn mi ẹnìkan tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, bàtà ẹni tí èmi kò tó gbé. Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitíìsì yín.

12 Ẹni ti ìmúga ìpakà Rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, yóò gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀, yóò kó ọkà rẹ̀ sínú àká, ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.”

Ìtẹ̀bọmi Jésù

13 Nígbà náà ni Jésù ti Gálílì wá sí odò Jọ́dánì kí Jòhánù báà lè ṣe ìtẹ̀bọmi fún un.

14 Ṣùgbọ́n Jòhánù kò fẹ́ ṣe ìtẹ̀bọmi fún un, ó wí pé, “Ìwọ ni ì bá ṣe ìbamitíìsì fún mi, ṣé ìwọ tọ̀ mí wá fún ìbamitíìsì?”

15 Jésù sì dáhùn pé, “Jọ̀wọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà, ní torí bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ fún wa láti mú gbogbo òdodo ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Jòhánù gbà, ó sì ṣe ìbamitíìsì fún un.

16 Bí a si tí ṣe ìtẹ̀bọmi fún Jésù tán, Ó jáde láti inú omi. Ní àkókò náà ọ̀run sí sílẹ̀, Ó sì rí Ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà àti bi mọ̀nàmọ́ná sórí rẹ̀.

17 Ohùn kan láti ọ̀run sì wí pé, “Èyí ni ọmọ mi, ẹni ti mo fẹ́ràn, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28