Mátíù 26 BMY

Ìdìtẹ̀ Mọ́ Jésù

1 Nígbà tí Jésù ti parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀, ó wí fún wọn pé,

2 “Bí ẹ̀yin tí mọ̀ ní ọjọ́ méjì sí i, àjọ ìrékọjá yóò bẹ̀rẹ̀. Àti pé, a ó fi Ọmọ-Ènìyàn lé ni lọ́wọ́, a ó sì kàn mí mọ́ àgbélébùú.”

3 Ní àsìkò tí Jésù ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn olórí àlùfàá àti àwọn àgbààgbà kó ara wọn jọ ní ààfin olórí àlùfàá náà tí à ń pè ní Káíáfà.

4 Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jésù pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á.

5 Ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé, “Kì í ṣe lásìkò àsè àjọ ìrékọjá, nítorí rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀.”

A fi Òróró Kun Jésù Lára ní Bẹ́tánì

6 Nígbà tí Jésù wà ní Bẹ́tánì ní ilé ọkùnrin tí à ń pè ní Símónì adẹ́tẹ̀;

7 Bí ó ti ń jẹun, obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìgò òróró ìkunra iyebíye, ó sì dà á sí i lórí.

8 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yin rí i, inú bí wọn. Wọ́n wí pé, “Irú ìfowóṣòfò wo ni èyí?

9 È é ha ti ṣe, obìnrin yìí ìbá tà á ní owó púpọ̀, kí a sì fi owó náà fún àwọn aláìní.”

10 Jésù ti mọ èrò ọkàn wọn, ó wí pé, “È é ṣe ti ẹ̀yin fi ń dá obìnrin yìí lẹ́bi? Ó ṣe ohun tí ó dára fún mi

11 Ẹ̀yin yóò ní àwọn aláìní láàrin yín nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n, ẹ̀yin kò le rí mi nígbà gbogbo.

12 Nípa dída òróró ìkunra yìí sí mi lára, òun ń ṣe èyí fún ìsìnkú mi ni.

13 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, a ó sì máa ṣe ìrántí rẹ̀ nígbà gbogbo fún ìṣesí rẹ̀ yìí. Níbikíbi tí a bá ti wàásù ìyìn rere yìí ní gbogbo àgbáyé ni a ó ti sọ ìtàn ohun tí obìnrin yìí ṣe.”

Júdásì Gbà Láti fi Jésù Hàn

14 Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn àpósítélì méjìlá ti à ń pè ní Júdásì Ìskáríọ́tù lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.

15 Òun sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin yóò san fún mi bí mo bá fi Jésù lé yín lọ́wọ́?” Wọ́n sì fún un ní ọgbọ́n owó fàdákà. Ó sì gbà á.

16 Láti ìgbà náà lọ ni Júdásì ti bẹ̀rẹ̀ sí i wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.

Oúnjẹ Alẹ́ Ìkẹyìn

17 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ àkàrà àìwú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ Jésù wá pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a pèsè sílẹ̀ láti jẹ àsè ìrékọjá?”

18 Jésù sì dáhùn pé, “Ẹ wọ ìlú lọ, ẹ̀yin yóò rí ọkùnrin kan, ẹ wí fún un pé, ‘Olùkọ́ wa wí pé: Àkókò mi ti dé. Èmi yóò sì jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ní ilé rẹ.’ ”

19 Nítorí náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú oúnjẹ àsè ti ìrékọjá níbẹ̀.

20 Ní àṣálẹ́ ọjọ́ kan náà, bí Jésù ti jókòó pẹ̀lú àwọn méjìlá,

21 nígbà tí wọ́n sì ń jẹun, ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀kan nínú yín yóò fi mí hàn.”

22 Ìbànújẹ́ sì bo ọkàn wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i bi í pé, “Olúwa, èmi ni bí?”

23 Jésù dáhùn pé, “Ẹni ti ó bá mi tọwọ́ bọ inú àwo, ni yóò fi mi hàn.

24 Ọmọ-Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà lọ́wọ́ ẹni tí a ó ti fi Ọmọ ènìyàn hàn! Ìbá kúkú sàn fún ẹni náà, bí a kò bá bí.”

25 Júdásì, ẹni tí ó fi í hàn pẹ̀lú béèrè pé, “Ráábì, èmi ni bí?”Jésù sì dá a lóhùn pé, “Ìwọ wí i”

26 Bí wọ́n ti ń jẹun, Jésù sì mú ìwọ̀n àkàrà kékeré kan, lẹ́yìn tí ó ti gbàdúrà sí i, ó bù ú, Ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ó wí pé, “Gbà, jẹ; nítorí èyí ni ara mi.”

27 Bákan náà, ó sì mú aago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sí fún wọn. Ó wí pé, “Kí gbogbo yín mu nínú rẹ̀.

28 Nítorí èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi, tí ó ń ṣe májẹ̀mú titun, tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn.

29 Sì kíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ mi. Èmi kì yóò tún mu nínú ọtí wáìnì yìí mọ́ títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò mu ún ní titun pẹ̀lú yín ní ìjọba Baba mi.”

30 Wọ́n sì kọ orin kan, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sórí òkè Ólífì.

Jésù sọ pé Pétérù yóò sẹ́ Òun

31 Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni yóò kọsẹ̀ lára mi ní òru òní. Nítorí a ti kọ ọ́ pé:“ ‘Èmi yóò kọlu olùsọ́ àgùntàna ó sì tú agbo àgùntàn náà ká kiri.’

32 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mo bá jí dìde, èmi yóò ṣáájú yín lọ sí Gálílì.”

33 Pétérù sì dá a lóhùn pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀.”

34 Jésù wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ pé, ní òru yìí, kí àkùkọ kí ó tó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.”

35 Pétérù wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ láti kú pẹ̀lú, èmi kò jẹ́ sẹ́ ọ.” Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí.

Jésù ní Gétísímánì

36 Nígbà náà ni Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibi kan ti à ń pè ní ọgbà Gétísémánì, ó wí fún wọn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbàdúrà lọ́hùn-ún ni.”

37 Ó sì mú Pétérù àti àwọn ọmọ Sébédè méjèèjì Jákọ́bù àti Jòhánù pẹ̀lú rẹ̀, ìrora àti ìbànújẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí i gba ọkà rẹ̀.

38 Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi gbọgbẹ́ pẹ̀lú ìbànújẹ́ títí dé ojú ikú, ẹ dúró níhìn-ín yìí, kí ẹ máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”

39 Òun lọ sí iwájú díẹ̀ sí i, ó sì dojú bolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé, “Baba mi, bí ó bá ṣeé se, jẹ́ kí a mú aago yìí ré mi lórí kọjá, ṣùgbọ́n ìfẹ́ tìrẹ ni mo fẹ́ kí ó ṣẹ, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.”

40 Bí ó ti padà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó bá wọn, wọ́n ń sùn. Ó kígbe pé, “Pétérù, ẹ̀yin kò tilẹ̀ lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan?

41 Ẹ kún fún ìṣọ́ra, kí ẹ sì máa gbàdúrà kí ẹ̀yin má ba à bọ́ sínú ìdẹ́wò. Nítorí Ẹ̀mi ń fẹ́ nítòótọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.”

42 Ó tún fi wọ́n sílẹ̀ nígbà kejì, ó sí gbàdúrà pé, “Baba mi, bí aago yìí kò bá lè ré mi lórí kọjá àfi tí mo bá mu ún, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe.”

43 Nígbà tí ó tún padà dé sọ́dọ̀ wọn, Ó rí i pé wọn ń sùn, nítorí ojú wọn kún fún oorun.

44 Nítorí náà, ó fi wọn sílẹ̀ ó tún padà lọ láti gbàdúrà nígbà kẹta, ó ń wí ohun kan náà.

45 Nígbà náà ni ó tọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó wí pé, “Àbí ẹ̀yin sì ń sùn síbẹ̀, ti ẹ sì ń sinmi? Wò ó sánmọ̀ wákàtí náà tí dé ti a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́.

46 Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a máa lọ! Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mi hàn ń bọ̀ wá!”

A mú Jésù

47 Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Júdásì, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá dé pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́ wọn, wọ́n ti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfàá àti àgbààgbà Júù wá.

48 Ẹni tí ó sì fi í hàn ti fi àmì fún wọn, pé, “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fi ẹnu kò ní ẹnu, òun náà ni; ẹ mú un.”

49 Nísinsìn yìí, Júdásì wá tààrà sọ́dọ̀ Jésù, ó wí pé, “Àlàáfíà, Ráábì” ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

50 Jésù wí pé, “Ọ̀rẹ́, kí ni nǹkan tí ìwọ bá wá.”Àwọn ìyókù sì sún ṣíwájú wọ́n sì mú Jésù.

51 Sì wò ó, ọ̀kan nínú àwọn tí ó wà pẹ̀lú Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fa idà yọ, ó sì ṣá ọ̀kan tí i ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé e ní etí sọnù.

52 Jésù wí fún un pé, “Fi idà rẹ bọ àkọ̀ nítorí àwọn tí ó ń fi idà pa ni.

53 Ìwọ kò mọ̀ pé èmi lè béèrè lọ́wọ́ Baba mi kí ó fún mi ju légíónì (6,000) ańgẹ́lì méjìlá? Òun yóò sì fi wọ́n ránṣẹ́ lẹsẹ̀kẹsẹ̀.

54 Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe eléyìí ọ̀nà wo ni a ó fi mú ìwé Mímọ́ ṣẹ, èyí tí ó ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nísinsìn yìí?”

55 Nígbà náà ni Jésù wí fún ìjọ ènìyàn náà pé, “Tàbí èmi ni ẹ kà sí ọ̀daràn ti ẹ múra pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ kí ẹ tó lé mú mi? Ẹ rántí pé mo ti wà pẹ̀lú yín, tí mo ń kọ́ yín lójoojúmọ́ nínú tẹ̀ḿpìlì, ẹ̀yin kò sì mú mi nígbà náà.

56 Ṣùgbọ́n gbogbo wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a tì ẹnu àwọn wòlíì sọ, tí a kọ sínú ìwé Mímọ́ lè ṣẹ.” Nígbà yìí gan-an ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sá lọ.

Níwájú Sahẹ́ńdírì

57 Àwọn tí ó mú Jésù fà á lọ sí ilé Káíáfà, olórí àlùfáà, níbi ti àwọn olúkọ́ òfin àti gbogbo àwọn àgbààgbà Júù péjọ sí.

58 Ṣùgbọ́n Pétérù ń tẹ̀lé e lókèèrè. Òun sì wá sí àgbàlá olórí àlùfáà. Ó wọlé, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùṣọ́. Ó ń dúró láti ri ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Jésù.

59 Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ Júù ní ilé-ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ti Júù pé jọ síbẹ̀, wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí tí yóò purọ́ mọ́ Jésù, kí a ba à lè rí ẹjọ́ rò mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, eléyìí tí yóò yọrí si ìdájọ́ ikú fún un.

60 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde, ṣùgbọ́n wọn kò rí ohun kan.Níkẹyìn, àwọn ẹlẹ́rìí méjì dìde.

61 Wọn wí pé, “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘èmi lágbára láti wó tẹ̀ḿpìlì Ọlọ́run lulẹ̀, èmi yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ mẹ́ta.’ ”

62 Nígbà náà ni olórí àlùfáà sì dìde, ó wí fún Jésù pé, “Ẹ̀rí yìí ńkọ́? Ìwọ sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ìwọ kò sọ bẹ́ẹ̀?”

63 Ṣùgbọ́n Jésù dákẹ́ rọ́rọ́.Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí fún un pé, “Mo fi ọ́ bú ní orúkọ Ọlọ́run alààyè: Kí ó sọ fún wa, bí ìwọ bá í ṣe Kírísítì Ọmọ Ọlọ́run.”

64 Jésù sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ wí,” Ṣùgbọ́n mo wí fún gbogbo yín. “Ẹ̀yin yóò rí Ọmọ-Ènìyàn ti yóò jókóó lọ́wọ́ ọ̀tún alágbára, tí yóò sì máa bọ̀ wá láti inú ìkùukù.”

65 Nígbà náà ni olórí àlùfáà fa aṣọ òun tikáraa rẹ̀ ya. Ó sì kígbe pé, “Ọ̀rọ̀ òdì! Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? Gbogbo yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òdì rẹ̀. Kí ni ìdájọ́ yín?”

66 Ki ni ẹ ti rò èyí sí.Gbogbo wọn sì kígbe lọ́hùn kan pé, “Ó jẹ̀bi ikú!”

67 Wọ́n tu itọ́ sí i ní ojú. Wọ́n gbá a lẹ́sẹ̀ẹ́. Àwọn ẹlòmíràn sì gbá a lójú.

68 Wọ́n wí pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wa! Ìwọ Kírísítì, Ta ni ẹni tí ó ń lù Ọ́?”

Pétérù ṣẹ́ Jésù

69 Lákòókò yìí, bí Pétérù ti ń jókòó ní ọgbà ìgbẹ́jọ́, ọmọbìnrin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Ìwọ wà pẹ̀lú Jésù ti Gálílì.”

70 Ṣùgbọ́n Pétérù ṣẹ̀ ní ojú gbogbo wọn pé “Èmi kò tilẹ̀ mọ ohun tí ẹ ń sọ nípa rẹ̀.”

71 Lẹ́yìn èyí, ní ìta lẹ́nu ọ̀nà, ọmọbìnrin mìíràn tún rí i, ó sì wí fún àwọn tí ó dúró yíká pé, “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jésù ti Násárẹ́tì.”

72 Pétérù sì tún ṣẹ́ lẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lú ìbúra pé, “Èmi kò tilẹ̀ mọ ọkùnrin náà rárá.”

73 Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó ń dúró níbi ìran yìí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, àwa mọ̀ ọ́. Èyí sì dá wa lójú nípa àmì ohùn rẹ̀ tí ó ń ti ẹnu rẹ jáde.”

74 Pétérù sì tún bẹ̀rẹ̀ sí íbúra ó sì fi ara rẹ̀ ré wí pé, “Mo ní èmi kò mọ ọkùnrin yìí rárá.”Lójú kan náà àkùkọ sì kọ.

75 Nígbà náà ni Pétérù rántí nǹkan tí Jésù ti sọ pé, “Kí àkùkọ tóó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.” Òun sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28