Mátíù 15 BMY

Ohun mímọ́ àti ohun àìmọ́

1 Nígbà náà ní àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ òfin tọ Jésù wá láti Jerúsálémù,

2 wọn béèrè pé, “Èé se tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ fi ń ṣe àìgbọ́ràn sí àwọn àṣà àtayébáyé Júù? Nítorí tí wọn kò wẹ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun!”

3 Jésù sì dá wọn lóhùn pé, “È é ha ṣe tí ẹ̀yin fi rú òfin Ọlọ́run, nítorí àṣà yín?

4 Nítorí Ọlọ́run wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún Baba òun ìyá rẹ,’ àtipé, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ òdì sí baba tàbí ìyá rẹ̀, ní láti kú.

5 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí fún baba tàbí ìyá rẹ̀ pé, “Ẹ̀bun fún Ọlọ́run i ohunkóhun tí ìwọ ìbá fi jèrè lára mi;”

6 tí Òun kò sì bọ̀wọ̀ fún baba tàbí ìyá rẹ̀,’ ó bọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin sọ ofin di asan nípa àṣà yín.

7 Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé:

8 “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi ẹnu lásán bu ọlá fún mi,ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré sí mi.

9 Lásán ni ìsìn wọn;nítorí pé wọ́n ń fi òfin ènìyan kọ́ ni ní ẹ̀kọ́.’ ”

10 Jésù pe ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ó wí pé, “Ẹ tẹ́tí, ẹ sì jẹ́ kí nǹkan tí mo sọ yé yín.

11 Ènìyàn kò di ‘aláìmọ́’ nípa ohun tí ó wọ ẹnu ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti ẹnu jáde wá ni ó sọ ni di ‘aláìmọ́.’ ”

12 Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún un pé, “Ǹjẹ́ ìwọ mọ̀ pé inú bí àwọn Farisí lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó sọ?” yìí

13 Jésù dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi ti ń bẹ ni ọ̀run kò bá gbìn ni á ó fà tu ti gbòǹgbò ti gbòǹgbò,

14 Ẹ fi wọ́n sílẹ̀; afọ́jú tí ń fi ọ̀nà han afọ́jú ni wọ́n. Bí afọ́jú bá sì ń fi ọ̀nà han afọ́jú, àwọn méjèèjì ni yóò jìn sí kòtò.”

15 Pétérù wí, “Ṣe àlàyé òwe yìí fún wa.”

16 Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èé ha ṣe tí ìwọ fi jẹ́ aláìmòye síbẹ̀”?

17 “Ìwọ kò mọ̀ pé ohunkóhun tí ó gba ẹnu wọlé, yóò gba ti ọ̀nà oúnjẹ lọ, a yóò sì yà á jáde?

18 Ṣùgbọ́n ohun tí a ń sọ jáde láti ẹnu, inú ọkàn ni ó ti ń wá, èyí sì ni ó ń sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’

19 Ṣùgbọ́n láti ọkàn ni èrò búburú ti wá, bí ìpanìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, irọ́ àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.

20 Àwọn tí a dárúkọ wọ̀nyí ni ó ń sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ Ṣùgbọ́n láti jẹun láì wẹ ọwọ́, kò lè sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ ”

21 Jésù sì ti ibẹ̀ kúrò lọ sí Tírè àti Sídónì.

22 Obìnrin kan láti Kénánì, tí ó ń gbé ibẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó ń bẹ̀bẹ̀, ó sì kígbe pé, “Olúwa, ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi; ọmọbìnrin mi ní ẹ̀mí èṣù ti ń dá a lóró gidigidi.”

23 Ṣùgbọ́n Jésù kò fún un ní ìdáhùn, Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á nìyànjú pé, “lé obìnrin náà lọ, nítorí ó ń kígbe tọ̀ wá lẹ́yìn.”

24 Ó dáhùn pé, “Àgùntàn ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí ó nù nìkan ni a rán mi sí”

25 Obìnrin náà wá, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ sí i pé, “Olúwa ṣàánú fún mi.”

26 Ó sì dáhùn wí pé, “Kò tọ́ kí a gbé oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”

27 Obìnrin náà sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ajá a máa jẹ èérún tí ó ti orí tábìlì olówó wọn bọ́ sílẹ̀.”

28 Jésù sì sọ fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ ńlá ni tìrẹ! A sì ti dáhùn ìbéèrè rẹ.” A sì mú ọmọbìnrin rẹ̀ lára dá ní wákàtí kan náà.

Jésù bọ́ ẹgbàajì ènìyàn (4,000)

29 Jésù ti ibẹ̀ lọ sí òkun Gálílì. Ó gun orí òkè, o sì jókòó níbẹ̀.

30 Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, àti àwọn arọ, afọ́jú, amúkùn-ún, odi àti ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn. Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jésù. Òun sì mú gbogbo wọn lárada.

31 Ẹnú ya ọ̀pọ̀ ènìyàn nígbà tí wọ́n rí àwọn odi tó ń sọ̀rọ̀, amúkùn-ún tó di alára pípé, arọ tí ó ń rìn àti àwọn afọ́jú tí ó ríran. Wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

32 Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó wí pé, “Àánú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí; nítorí wọ́n ti wà níhìn-ín pẹ̀lú mi fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko báyìí. Wọn kò sì tún ní oúnjẹ mọ́. Èmi kò fẹ́ kí wọn padà lébi, nítorí òyì lè kọ́ wọn lójú ọ̀nà.”

33 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì dá a lóhùn pé, “Níbo ni àwa yóò ti rí oúnjẹ ní ihà níhìn-ín yìí láti fi bọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí?”

34 Jésù sì béèrè pé, “ìsù Búrẹ́dì mélòó ni ẹ̀yín ní?”Wọ́n sì dáhùn pé, “Àwa ní ìsù àkàrà méje pẹ̀lú àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀.”

35 Jésù sì sọ fún gbogbo ènìyàn kí wọn jókòó lórí ilẹ̀.

36 Òun sì mú ìsù àkàrà méje náà àti ẹja náà. Ó sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run, ó bù wọ́n sì wẹ́wẹ́, ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì pín in fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà.

37 Gbogbo wọn jẹ, wọ́n sì yó. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì sa èyí tókù, ẹ̀kún agbọ̀n méje ni èyí tó sẹ́kù jẹ́

38 Gbogbo wọn sì jẹ́ ẹgbàají: (4000) ọkùnrin láì kan àwọn obìnrin àti ọmọdé.

39 Lẹ́yìn náà, Jésù rán àwọn ènìyàn náà lọ sí ilé wọn, ó sì bọ́ sínú ọkọ̀, ó ré kọjá sí Mágádánì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28