Mátíù 4 BMY

Ìdánwò Jésù

1 Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ darí Jésù sí ihà láti dán an wò láti ọwọ́ èsù.

2 Lẹ́yìn tí Òun ti gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi sì ń pa á.

3 Nígbà náà ni olùdánwò tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ kí àwọn òkúta wọ̀nyí di àkàrà.”

4 Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn pé, “A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípa àkàrà nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ ti ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wá.’ ”

5 Lẹ́yìn èyí ni èṣù gbé e lọ sí ìlú mímọ́ náà; ó gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹ̀ḿpìlì.

6 Ó wí pé, “Bí ìwọ̀ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, Bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ. A sa ti kọ̀wé rẹ̀ pé:“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ nítorí tìrẹwọn yóò sì gbé ọ sókè ni ọwọ́ wọnkí ìwọ kí ó má baà fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”

7 Jésù sì da lóhùn, “A sìáà ti kọ ọ́ pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”

8 Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo orílẹ̀-èdè ayé àti gbogbo ẹwà wọn hàn án.

9 Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.”

10 Jésù wí fún un pé, “Kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, ìwọ Sàtánì! Nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ ó sìn.’ ”

11 Nígbà náà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àwọn ańgẹ́lì sì tọ̀ ọ́ wá láti jísẹ́ fún un.

Jésù Bẹ̀rẹ̀ Sí Wàásù

12 Nígbà tí Jésù gbọ wí pé a ti fi Jòhánù sínu túbú ó padà sí Gálílì.

13 Ó kúrò ní Násárẹ́tì, ó sì lọ ígbé Kápánámù, èyí tí ó wà létí òkun Sébúlónì àti Náfítálì.

14 Kí èyí tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ pé:

15 “Iwọ Sébúlónì àti ilẹ̀ Náfítalìọ̀nà tó lọ sí òkun, ní ọ̀nà Jọ́dánì,Gálílì ti àwọn aláìkọlà,

16 Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùntí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá,àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì ikuni ìmọ́lẹ̀ tan fún.”

17 Láti ìgbà náà lọ ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronú pìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”

Pípe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Àkọ́kọ́.

18 Bí Jésù ti ń rìn létí òkun Gálílì, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Símónì, ti à ń pè ní Pétérù, àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń ju sọ àwọn wọn sínú òkun nítorí apẹja ni wọ́n.

19 Jésù wi fun wọn pé, “Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”

20 Lójú kan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀lé e.

21 Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti Jòhánù, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú Sébédè baba wọn, wọ́n ń dẹ àwọ̀n wọn, Jésù sì pè wọn náà pẹ̀lú.

22 Lójú kan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú-omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

Jésù ṣe ìwòsàn.

23 Jésù sì rin káàkiri gbogbo Gálílì, ó ń kọ́ni ní sínágọ́gù, ó ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba ọ̀run. ó sì ń ṣe ìwòsàn àrùn gbogbo àti àìsàn láàrin gbogbo ènìyàn.

24 Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Síríà ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú àrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn.

25 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Gálílì, Dékápólì, Jerúsálémù, Jùdíà, àti láti òkè odò Jọ́dánì sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28