Mátíù 17 BMY

Orí Òkè Ìparadà

1 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà, Jésù mú Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ Jákọ́bù, ó mú wọn lọ sí orí òkè gíga kan tí ó dá dúró.

2 Níbẹ̀ ara rẹ̀ yí padà níwájú wọn; Ojú rẹ̀ sì ràn bí oòrùn, aṣọ rẹ̀ sì funfun bí ìmọ́lẹ̀.

3 Lójijì, Mósè àti Èlíjà fara hàn, wọ́n sì ń bá Jésù sọ̀rọ̀.

4 Pétérù sọ fún Jésù pé, “Olúwa, jẹ́ kí a kúkú máa gbé níhìn-ín yìí. Bí ìwọ bá fẹ́, èmi yóò pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mósè, àti ọ̀kan fún Èlíjà.”

5 Bí Pétérù ti sọ̀rọ̀ tán, àwọ̀sánmọ̀ dídán síji bò wọ́n, láti inú rẹ̀ ohùn kan wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni ti inú mi dùn sí gidigidi. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!”

6 Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbọ́ èyí, wọ́n dojú bolẹ̀. Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.

7 Ṣùgbọ́n Jésù sì tọ̀ wọ́n wá. Ó fi ọwọ́ kàn wọ́n, ó wí pé, “Ẹ dìde, ẹ má ṣe bẹ̀rù.”

8 Nígbà tí wọ́n sì gbé ojú wọn sókè, tí wọ́n sì wò ó, Jésù nìkan ni wọn rí.

9 Bí wọ́n sì ti ń sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè, Jésù pàṣẹ fún wọn pé “Ẹ kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni ohun tí ẹ rí, títí ọmọ-ènìyàn yóò fi jí dìde kúrò nínú òkú”

10 Àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ́ pé, “Kí ni ó fà á tí àwọn olùkọ́ òfin fi ń wí pé, Èlíjà ní láti kọ́ padà wá”

11 Jésù sì dáhùn pé, “Dájúdájú òtítọ́ ni wọ́n ń sọ. Èlíjà wá láti fi gbogbo nǹkan sí ipò.

12 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín lóòótọ́; Èlíjà ti dé. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ ọ́n, ọ̀pọ̀ tilẹ̀ hu ìwà búburú sí i. Bákan náà, Ọmọ ènìyàn náà yóò jìyà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú.”

13 Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ̀ pé ó n sọ̀rọ̀ nípa Jòhánù onítẹ̀bọmi fún wọn ni.

Ìwòsàn ọmọkùnrin ẹlẹ́mí èṣù

14 Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ ìjọ ènìyàn,. ọkùnrin kan tọ̀ Jésù wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí pé,

15 “Olúwa, ṣàánú fún ọmọ mi, nítorí tí ó ní wárápá. Ó sì ń joró gidigidi, nígbà púpọ̀ ni ó máa ń ṣubu sínú iná tàbí sínú omi.

16 Mo sì ti mú un tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò lè wò ó sàn.”

17 Jésù sì dáhùn wí pé, “A! ẹ̀yìn alágídí ọkàn àti aláìgbàgbọ́ ènìyàn, èmi yóò ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi ó sì ti fara dà á fún yín tó? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín yìí.”

18 Nígbà náà ni Jésù bá ẹ̀mí èṣù tí ó ń bẹ nínú ọmọkùnrin náà wí, ó sì fi í sílẹ̀, à mú ọmọkùnrin náà láradá láti ìgbà náà lọ.

19 Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi Jésù níkọ̀kọ̀ pé, “È é ṣe tí àwa kò lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?”

20 Jésù sọ fún wọn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré. Lóòòtọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí músítadì, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, ‘Ṣípò kúrò níhìn-ín yìí’ òun yóò sì sí ipò. Kò sì nií sí ohun tí kò níí ṣe é ṣe fún yín.”

21 Ṣùgbọ́n irú ẹ̀mí èṣù yìí kò ní lọ, bí kò ṣe nípa ààwẹ̀ àti àdúrà.

22 Nígbà tí wọ́n sì ti wà ní Gálílì, Jésù sọ fún wọn pé, “Láìpẹ́ yìí a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́.

23 Wọn yóò sì pa á, ní ọjọ́ kẹ́ta lẹ́yìn èyí, yóò sì jí dìde sí ìyè.” Ọkàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì kún fún ìbànújẹ́ gidigidi.

Owó Tẹ́ḿpìlì

24 Nígbà tí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì dé Kápánámù, àwọn agbowó-òde tọ Pétérù wá wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ Olúwa yín ń dá owó tẹ̀ḿpìlì?”

25 Pétérù sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń san.”Nígbà tí Pétérù wọ ilé láti bá Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Jésù ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, Jésù bí i pé, “Kí ni ìwọ rò, Símónì? Ǹjẹ́ àwọn ọba ń gba owó-orí lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí lọ́wọ́ àwọn àlejò?”

26 Pétérù dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àwọn àlejò ni.”Jésù sì tún wí pé, “Èyí jẹ́ wí pé àwọn ọmọ onílẹ̀ kì í san owó-òde?

27 ‘Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, àwa kò fẹ́ mú wọn bínú’ Nítorí náà, ẹ lọ sí etí òkun, kí ẹ sì sọ ìwọ̀ sí omi. Ẹ mú ẹja àkọ́kọ́ tí ẹ kọ́ fà sókè, ẹ ya ẹnu rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì rí owó idẹ kan níbẹ̀, ki ẹ fi fún wọn fún owó-orí tèmi àti tirẹ̀.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28