Mátíù 7 BMY

Ṣíṣe Ìdájọ́ Ẹnìkejì

1 “Ẹ má ṣe dáni lẹ́jọ́, kí a má bà dá yín lẹ́jọ́.

2 Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni a ó sì ṣe fún yín; irú òṣùnwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ̀n, òun ni a ó sì fi wọ̀n fún yín

3 “È é tí ṣe tí ìwọ fi ń wo èrúnrún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyè sí ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ?

4 Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ni ojú rẹ,’ sì wò ó ìtì igi ń bẹ ní ojú ìwọ tì kara rẹ.

5 Ìwọ àgàbàgebè, tètè kọ́ yọ ìtì igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì tó ríran kedere láti yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arakùnrin rẹ kúrò.

6 “Ẹ má ṣe fi ohun mímọ́ fún ajá jẹ, ẹ má sì ṣe sọ ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye yín fún ẹlẹ́dẹ̀, bí ẹ̀yin bá se bẹ́ẹ̀ kí wọ́n má bà fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn a sì yí padà sí yín, wọn a sì bù yín jẹ.

Béèrè, Kànkùn, Wá kiri

7 “Béèrè, a ó sì fi fún yín; wá kiri, ẹ̀yin yóò sì rí; kànkùn, a ó sì sí i sílẹ̀ fún yín.

8 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó béèrè ń rí gbà, ẹni tí ó bá sì wà kiri ń ní, ẹni bá sì kànkùn ni a ó ò si sílẹ̀ fún.

9 “Ta ni ọkùnrin náà tí ń bẹ nínú yín, bí ọmọ rẹ̀ béèrè àkàrà, tí yóò jẹ́ fi òkúta fún un?

10 Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò jẹ́ fún un ní ejò?

11 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí í ṣe ènìyàn búburú bá mọ̀ bí a ti í fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ohun rere fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?

12 Nítorí náà, nínú gbogbo ohunkóhun ti ẹ̀yin bá ń fẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́; nítorí èyí ni òfin àti àwọn wòlíì.

Ọ̀nà-tóóró àti Ọ̀nà-gbòòrò

13 “Ẹ máa ba ẹnu-ọ̀nà tóótó wọlé; gbòòrò ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti oníbùú ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹni tí ń bá ibẹ̀ wọlé.

14 Nítorí kékeré ni ẹnu-ọ̀nà náà, tóóró sì ni ojú ọ̀nà náà, ti ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹni tí ó ń rìn ín.

Igi Àti Èso rẹ̀

15 “Ẹ máa sọ́ra fún àwọn èké wòlíì tí wọ́n ń tọ̀ yín wá ní àwọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọn apanijẹ ìkookò ni wọ́n.

16 Nípa èso wọn ni a ó fi dá wọn mọ̀. Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára ẹ̀gún ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún èṣùṣú?

17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú.

18 Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere.

19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, à gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná.

20 Nítorí náà, èso wọn ni ẹ̀yin yóò fi dá wọn mọ̀.

21 “Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.

22 Ọ̀pọ̀ ni yóò wí fún mi ní ọjọ́ náà pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, àti ní orúkọ rẹ kọ́ ni a fi re ọ̀pọ̀ ẹ̀mú ẹ̀sù jáde, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu?’

23 Nígbà náà ni èmi yóò wí fún wọn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí, ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’

Ọlọ́gbọ́n Àti Òmùgọ̀ Ọ̀mọ̀lé

24 “Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fi wé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta.

25 Òjò sì rọ̀, ikún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sí bì lu ilé náà; síbẹ̀ síbẹ̀ náà kò sì wó, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta.

26 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí kò bá sì ṣe wọ́n, òun ni èmi yóò fi wé aṣiwèrè ènìyàn kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn.

27 Òjò sì rọ̀, ìkú n omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ilé náà sì wó; ìwó rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ.”

28 Nígbà tí Jésù sì parí sisọ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu ya àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀,

29 Nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí i ti olùkọ́ òfin wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28