Mátíù 5 BMY

Ìwàásù Orí Òkè

1 Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó gun orí òkè lọ ó sì jókòó. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ si tọ̀ ọ́ wá.

2 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn wí pé:

3 “Alábùkún-fún ni àwọn òtòsì ní ẹ̀mí,nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.

4 Alábùkún-fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀,nítorí a ó tù wọ́n nínú.

5 Alábùkún-fún ni àwọn ọlọ́kàn tútù,nítorí wọn yóò jogún ayé.

6 Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń patí òùngbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó.

7 Alábùkún-fún ni àwọn aláàánú,nítorí wọn yóò rí àánú gbà.

8 Alábùkún-fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́,nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.

9 Alábùkún-fún ni àwọn tonílàjà,nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.

10 Alábùkún-fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí,nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodonítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run.

11 “Alábùkún-fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, ti wọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi.

12 Ẹ yọ̀, kí ẹ̀yin sì fò fún ayọ, nítorí ńlá ni èrè yín ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ń bẹ ṣáájú yín.

Iyọ̀ Àti Ìmọ́lẹ̀.

13 “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn? Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dà á nù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14 “Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè fara sin.

15 Bẹ́ẹ̀ ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì gbé e sí abẹ́ òṣùnwọ̀n; bí kò ṣe sí orí ọ̀pá fìtílà, a sì tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé.

16 Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo.

Ìmúṣẹ Òfin

17 “Ẹ má se rò pé, èmí wá láti pa òfin àwọn wòlíì run, èmi kò wá láti pa wọn rẹ́, bí kò ṣe láti mú wọn ṣẹ.

18 Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, àmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé ofin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ.

19 Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jù lọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jù lọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń sewọn, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run.

20 Nítorì náà ni mọ ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisí àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run.

Ìpànìyàn

21 “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ẹnikẹni tí ó bá pànìyàn yóò wà nínú ewu ìdájọ́.’

22 Ṣùgbọ́n èmi wí fún un yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bínú sí arákùnrin rẹ̀ yóò wà nínú ewu ìdájọ́. Ẹnikẹ́ni ti ó ba wí fun arakùnrin rẹ̀ pé, ‘Ráákà’ yóò fara hàn níwájú Sahẹ́ńdìrì; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá wí pé ‘Ìwọ wèrè!’ yóò wà nínú ewu iná ọ̀run àpáàdì.

23 “Nítorí náà, nígbà tí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ wá ṣíwájú pẹpẹ, bí ìwọ bá sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ̀ ni ohùn kan nínú sí ọ.

24 Fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ. Ìwọ kọ́kọ́ lọ ṣe ìlàjà láàrin ìwọ àti arákùnrin rẹ̀ na. Lẹ́yìn náà, wá kí ó sì fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀.

25 “Bá ọ̀tá rẹ làjà kánkán, ẹni tí ó ń gbé ọ lọ sílé ẹjọ́. Ṣe é nígbà ti ó wà ní ọ̀nà pẹ̀lú rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò fà ọ́ lé onídajọ lọ́wọ́, onídájọ́ yóò sí fá ọ lé àwọn ẹ̀sọ́ lọ́wọ́, wọ́n a sì sọ ọ́ sínú túbú.

26 Lóòótọ ni mo wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀ títítí ìwọ yóò fi san ẹyọ owó kan tí ó kù.

Panṣágà

27 “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.’

28 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìrinrin kan ní ìwòkuwò, ti bà a ṣe panṣágà ná ní ọkàn rẹ̀.

29 Bí ojú rẹ ọ̀tún bá mú ọ dẹ́sẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sàn kí ẹ̀ya ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sínú iná ọ̀run àpáàdì.

30 Bí ọwọ́ rẹ ọ̀tún bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀ gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sàn kí ẹ̀ya ara rẹ kan ṣègbé ju kí gbogbo ara rẹ lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì.

Ìkọ̀sílẹ̀

31 “A ti wí pẹ̀lú pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ gbọdọ̀ fún un ní ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀.’

32 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀, àfi nítorí àgbèrè, mú un se àgbèrè, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fẹ́ obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ ní ìyàwó ṣe àgbèrè.

Ìbúra

33 “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàani pé; ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ búrá èké bí kò ṣe pé kí ìwọ kí ó mú ìbúra rẹ̀ sí Olúwa ṣẹ.’

34 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, Ẹ má ṣe búra rárá,: ìbáà ṣe ìfi-ọ̀run-búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni.

35 Tàbí ìfi-ayé-búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerúsálémù, nítorí olórí ìlú Ọba Ńlá ni.

36 Má ṣe fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun ẹyọ kan di funfun tàbí di dúdú.

37 Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, ohunkóhun tí ó ba ju ìwọ̀nyí lọ, wá láti ọ̀dọ̀ ẹni ibi.

Ojú Fún Ojú

38 “Ẹ̀yin tí gbọ́ bí òfin tí wí pé, ‘Ojú fún ojú àti eyín fún eyín.’

39 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ‘Ẹ má ṣe tako ẹni ibi. Bí ẹnì kan bá gbá ọ lẹ́rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ òsì sí olúwa rẹ̀ pẹ̀lú.

40 Bí ẹnì kan bá fẹ́ gbé ọ lọ sílé ẹjọ́, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú.

41 Bí ẹni kan bá fẹ́ fi agbára mú ọ rìn ibùsọ̀ kan, bá a lọ ní ibùsọ̀ méjì.

42 Fi fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún ẹni tí ó fẹ́ ya láti lọ́wọ́ rẹ.

Fẹ́ràn Ọ̀ta Rẹ

43 “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Fẹ́ràn aládúgbo rẹ, kí ìwọ sì kórírà ọ̀ta rẹ̀.’

44 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀ta yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín,

45 Kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọmọ Baba yín bi ń bẹ ní ọ̀run. Ó mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti ènìyàn rere, ó rọ̀jò fún àwọn olódodo àti fún àwọn aláìṣòdodo.

46 Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan, èrè kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn agbowó-òde kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́?

47 Àti bí ó bá sì jẹ́ pé kìkì àwọn arákùnrin yín nìkan ni ẹ̀yin ń kí, kín ni ẹ̀yin ń ṣe ju àwọn mìíràn? Àwọn abọ̀rìṣà kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí?

48 Nítorí náà, ẹ jẹ́ pípé, gẹ́gẹ́ bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ṣe jẹ́ pípé.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28