1 Ní àkókò náà ni Hẹ́rọ́dù ọba Tẹ́tírákì gbọ́ nípa òkìkí Jésù,
2 ó wí fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Dájúdájú Jòhánù onítẹ́bọmi ni èyí, ó jíǹde kúrò nínú òkú. Ìdí nìyí tí ó fi ní agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí.”
3 Nísìnsin yìí Hẹ́rọ́dù ti mú Jòhánù, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Hẹ́rọ́díà aya Fílípì arákùnrin rẹ̀,
4 nítorí Jòhánù onítẹ̀bọmi ti sọ fún Hẹ́rọ́dù pé, “Kò yẹ fún ọ láti fẹ́ obìnrin náà.”
5 Hẹ́rọ́dù fẹ pa Jòhánù, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rù àwọn ènìyàn nítorí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé wòlíì ni.
6 Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Hẹ́rọ́dù, ọmọ Hẹ́rọ́díà obìnrin jó dáadáa, ó sì tẹ́ Hẹ́rọ́dù lọ́run gidigidi.
7 Nítorí náà, Hẹ́rọ́dù jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún.
8 Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Jòhánù onítẹ̀bọmi nínú àwo pọ̀kọ́”.
9 Inú ọba bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀jẹ́ rẹ̀ àti kí ojú má ba à tì í níwájú àwọn àlejò tó wà ba jẹ àsè, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́.
10 Nítorí náà, a bẹ́ orí Jòhánù onítẹ̀bọmi nínú ilé túbú.
11 A sì gbé orí rẹ̀ jáde láti fi fún ọmọbìnrin náà nínú àwo pọ̀kọ́, òun sì gbà á, ó gbé etọ ìyá rẹ̀ lọ.
12 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù wá gba òkú rẹ̀, wọ́n sì sin ín. Wọ́n sì wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jésù.
13 Nígbà tí Jésù gbọ́ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó kúrò níbẹ̀, ó bá ọkọ̀ ojú-omi lọ sí ibi kọ́lọ́fin kan ní èbúté láti dá wà níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn si fi ẹṣẹ̀ rìn tẹ̀lé e láti ọ̀pọ̀ ìlú wọn.
14 Nígbà ti Jésù gúnlẹ̀, tí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ yọ́ sí wọn, ò sì mú àwọn aláìsàn láradá.
15 Nígbà ti ilẹ̀ ń sú lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí pé, “Ibi yìí jìnnà sí ìlú ilẹ̀ sì ń ṣú lọ. Rán àwọn ènìyàn lọ sí àwọn ìletò kí wọ́n lè ra oúnjẹ jẹ.”
16 Ṣùgbọ́n Jésù fèsì pé, “Kò nílò kí wọ́n lọ kúrò. Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”
17 Wọ́n sì da lóhùn pé, “Àwá kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì lọ níhìn-ín.”
18 Ó wí pé, “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí.”
19 Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-un àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn.
20 Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá.
21 Iye àwọn ènìyàn ni ọjọ́ náà jẹ́ ẹgbẹẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ọkùnrin, Láì ka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.
22 Lẹ́sẹ̀kẹ́sẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n bọ sínú ọkọ̀ wọn, àti kí wọ́n máa kọjá lọ ṣáájú rẹ̀ sí òdì kejì. Òun náà dúró lẹ́yìn láti tú àwọn ènìyàn ká lọ sí ilé wọn
23 Lẹ́yìn tí ó tú ìjọ ènìyàn ká tán, ó gun orí òkè lọ fúnra rẹ̀ láti lọ gba àdúrà. Nígbà tí ilẹ̀ sú, óun wà ni nìkan níbẹ̀,
24 ní àkókò yìí ọkọ ojú-omi náà ti rin jìnnà sí etí bèbè òkun, tí ìjì omi ń tì í síwá sẹ́yìn, nítorí ìjì ṣe ọwọ́ òdì sí wọn.
25 Ní déédé agogo mẹ́rin òwúrọ̀, Jésù tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi.
26 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé “iwin ni” wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù.
27 Lójú kan náà, Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.”
28 Pétérù sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.”
29 Jésù dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.”Nígbà náà ni Pétérù sọ̀ kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jésù.
30 Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó kígbe lóhùn rara pé, “Gbà mí, Olúwa.”
31 Lójú kan náà, Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó dì í mú, ó sì gbà á. Ó sì wí fún un pé, “Èé ṣe tí ìwọ fi ṣiyè méjì ìwọ onígbàgbọ́ kékeré?”
32 Àti pé, nígbà ti wọ́n sì gòkè sínú ọkọ̀, ìjì náà sì dúró jẹ́ẹ́.
33 Nígbà náà ni àwọn to wà nínú ọkọ̀ náà forí balẹ̀ fún un wọ́n wí pé, “nítòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe.”
34 Nígbà tí wọn ré kọjá sí apá kejì wọ́n gúnlẹ̀ sí Gẹ́nẹ́sárẹ́tì.
35 Nígbà ti wọn mọ̀ pé Jésù ni, wọn sì ránṣẹ́ sí gbogbo ìlú náà yíká. Wọ́n sì gbé gbogbo àwọn aláìsàn tọ̀ ọ́ wá.
36 Àwọn aláìsàn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gba àwọn láyè láti fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sì rí ìwòsàn.