1 Ní àkókò náà ni Jésù ń la àárin oko ọkà kan lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ebi sì ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i ya orí ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́.
2 Nígbà tí àwọn Farisí rí èyí. Wọ́n wí fún pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi.”
3 Jésù dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò ha ka ohun tí Dáfídì se nígbà tí ebi ń pa á àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.
4 Ó wọ inú ilé Ọlọ́run, òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àkàrà tí a yà sọ́tọ̀, èyí tí kò yẹ fún wọn láti jẹ, bí kò se fún àwọn àlùfáà nìkan.
5 Tàbí ẹ̀yin kò ti kà á nínú òfin pé ní ọjọ́ ìsinmi, àwọn àlùfáà tí ó wà ní tẹ́ḿpílì ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ tí wọ́n sì wà láì jẹ̀bi.
6 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, ẹni tí ó pọ̀ ju tẹ́ńpílì lọ wà níhìn-ín.
7 Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí, ‘Àánú ni èmi ń fẹ́ kì í se ẹbọ,’ ẹ̀yin kì bá tí dá aláìlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi.
8 Nítorí pé Ọmọ Ènìyàn jẹ́ Olúwa ọjọ́ ìsinmi.”
9 Nígbà tí Jésù kúrò níbẹ̀ ó lọ sí sínágọ́gù wọn,
10 ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ wà níbẹ̀. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jésù, wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ènìyàn láradá ní ọjọ́ ìsinmi?”
11 Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ wí pé bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ní àgùntàn kan ṣoṣo, tí ó sì bọ́ sínú kòtò ní ọjọ́ ìsinmi, tí kì yóò dì í mú, kí ó sì fà á jáde.
12 Ǹjẹ́ mélòó mèlòó ní ènìyàn ní iye lórí ju àgùntàn kan lọ! Nítorí náà ó yẹ láti ṣe rere ní ọjọ́ ìsinmi.”
13 Nígbà náà, ó sì wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ,” bí òun sì ti nà án, ọwọ́ rẹ̀ sì bọ̀ sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ìkejì.
14 Síbẹ̀ àwọn Farisí jáde lọ pe ìpàdé láti dìtẹ̀ mú un bí wọn yóò ṣe pa Jésù.
15 Ṣùgbọ́n Jésù mọ, ó yẹra kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú gbogbo àwọn aláìsàn láradá.
16 Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe sọ ẹni ti òun jẹ́.
17 Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àṣọtẹ́lẹ̀ èyí tí wòlíì Àìsáyà sọ nípa rẹ̀ pé:
18 “Ẹ wo ìránṣẹ mi ẹni tí mo yàn.Àyànfẹ́ mi ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi;èmi yóò fi ẹ̀mí mi fún un.Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ orílẹ̀-èdè gbogbo.
19 Òun kì yóò jà. bẹ́ẹ̀ ni kì yóò kígbe;ẹnikẹ́ni kì yóò gbọ́ ohùn rẹ ní ìgboro.
20 Ìyẹ́ tí ó fẹ́rẹ̀ fò ni kí yóò ṣẹ́,bẹ́ẹ̀ ni kì yóò pa iná fìtílà tí ó rú èéfín.Títí yóò fi mú ìdájọ́ dé ìsẹ́gun.
21 Ní orúkọ rẹ̀ ni gbogbo ayé yóò fi ìrètí wọn sí.”
22 Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹmí-èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi. Jésù sì mú un lára dá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran.
23 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn ènìyàn. Wọ́n wí pé, “Èyí ha lè jẹ́ Ọmọ Dáfídì bí?”
24 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisí gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Nípa Béélísébúbù nìkan, tí í ṣe ọba ẹ̀mí-èṣù ni ọkùnrin yìí fi lé àwọn ẹ̀mí-èṣù jáde”
25 Jésù tí ó mọ èrò wọn, ó wí fún wọn pé, “Ìjọba kíjọba tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ yóò parun, ìlú kílu tàbí ilé kílé tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ kì yóò dúró.
26 Bí èṣù bá sì ń lé èṣù jáde, a jẹ́ wí pé, ó ń yapa sí ara rẹ̀. Ìjọba rẹ yóò ha ṣe le dúró?
27 Àti pé, bi èmi bá ń lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù jáde nípa Béélísébúbù, nípa ta ni àwọn ènìyàn yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà ni wọn yóò ṣe má ṣe ìdájọ́ yín.
28 Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípa ẹ̀mí Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín.
29 “Tàbí, báwo ni ẹnikẹ́ni ṣe lè wọ ilé alágbára lọ kí ó sì kó ẹrù rẹ̀, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ de alágbára náà? Nígbà náà ni ó tó lè kó ẹrù rẹ̀ lọ.
30 “Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, òun lòdì sí mi, ẹni tí kò bá mi kó pọ̀ ń fọ́nká.
31 Nítorí èyí, mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀ òdì ni a yóò dárí rẹ̀ ji ènìyàn, ṣùgbọ́n ìsọ̀rọ̀-òdì-sí ẹ̀mí mímọ́ kò ní ìdáríjì.
32 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ọmọ ènìyàn, a ó dárí jì í, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dárí jì í, ìbá à ṣe ní ayé yìí tàbí ní ayé tí ń bọ̀.
33 “E ṣọ igi di rere, èso rẹ̀ a sì di rere tàbí kí ẹ sọ igi di búburú, èso rẹ a sì di búburú, nítorí nípa èso igi ni a ó fi mọ̀ ọ́n.
34 Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo ni ẹ̀yin tí ẹ jẹ búburú ṣe lè sọ̀rọ̀ rere? Ọkàn ènìyàn ni ó ń darí irú ọ̀rọ̀ tí ó lè jáde lẹ́nu rẹ̀.
35 Ẹni rere láti inú ìsúra rere ọkàn rẹ̀ ní i mú ohun rere jáde wá: àti ẹni búburu láti inú ìsúra búburú ni; mu ohun búburú jáde wá.
36 Ṣùgbọ́n, mo sọ èyí fún yín, ẹ̀yin yóò jíyìn gbogbo ìsọkúsọ yín ní ọjọ́ ìdájọ́.
37 Nítorí nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín ni a fi dá yin láre, nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín sì ni a ó fi dá yin lẹ́bi.”
38 Nígbà náà ni, díẹ̀ nínú àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ òfin wí fún pé “Olùkọ́, àwa fẹ́ rí iṣẹ́ àmì kan lọ́dọ̀ rẹ̀”.
39 Ó sì dá wọn lóhùn wí pé “Ìran búburú àti ìran panságà ń béèrè àmì; ṣùgbọ́n kò sí àmí tí a ó fi fún un, bí kò ṣe àmì Jónà wòlíì.
40 Bí Jónà ti gbé inú ẹja ńlá fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí Ọmọ Ènìyàn yóò gbé ní inú ilẹ̀ fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.
41 Àwọn ará Nínéfè yóò dìde pẹ̀lú ìran yìí ní ọjọ́ ìdájọ́. Wọn yóò sì dá a lẹ́bi. Nítorí pé wọ́n ronú pìwàdà nípa ìwàásù Jónà. Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀ jù Jónà wà níhìn-in yìí.
42 Ọbabìnrin gúsù yóò sì dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ sí ìran yìí yóò sì dá a lẹ́bi; nítorí tí ó wá láti ilẹ̀ ìkangun ayé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n láti ẹnu Sólóḿonì. Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀ jù Sólómónì ń bẹ níhìn-ín yìí.
43 “Nígbà tí ẹ̀mí búburú kan bá jáde lára ènìyàn, a máa rìn ní aṣálẹ̀, a máa wá ibi ìsinmi, kò sì ní rí i.
44 Nígbà náà ni ẹ̀mí yóò wí pé, ‘Èmi yóò padà sí ara ọkùnrin tí èmí ti wá.’ Bí ó bá sì padà, tí ó sì bá ọkàn ọkùnrin náà ni òfìfo, a gbà á mọ́, a sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́.
45 Nígbà náà ni ẹ̀mí ẹ̀ṣù náà yóò wá ẹ̀mí méje mìíràn tí ó burú ju òun lọ. Gbogbo wọn yóò sì wá sí inú rẹ̀, wọn yóò máa gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà a sì burú ju ti ìṣáájú lọ; Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí fún ìran búburú yìí pẹ̀lú.”
46 Bí Jésù ti ṣe ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wà lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀.
47 Nígbà náà ni ẹnì kan wí fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró dè ọ́ lóde wọ́n ń fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”
48 Ó sì fún ni èsì pé, “Ta ni ìyá mi? Ta ni àwọn arákùnrin mi?”
49 Ó nawọ́ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí pé, “Wò ó, ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni wọ̀nyí.”
50 Nítorí náà, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”