Mátíù 19 BMY

Ìkọsílẹ̀

1 Lẹ́yìn tí Jésù ti parí ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò ní Gálílì. Ó sì yípo padà sí Jùdíà, ó gba ìhà kejì odò Jọ́dánì.

2 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú wọn láradá níbẹ̀.

3 Àwọn Farisí wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti dán an wò. Wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nítorí ohunkóhun?”

4 Ó dáhùn pé, “A ti rí i kà pé ‘ní ìpilẹ̀sẹ, Ọlọ́run dá wọn ni ọkùnrin àti obìnrin.’

5 Ó sì wí fún un pé, Nítorí ìdí èyí ‘Ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sí da ara pọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì náà á sì di ara kan.’

6 Wọn kì í tún ṣe méjì mọ́, ṣùgbọ́n ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run bá ti so ṣọ̀kan, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà wọ́n.”

7 Wọ́n bi í pé: “Kí ni ìdí tí Mósè fi pàṣẹ pé, ọkùnrin kan lè kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nípa fífún un ní ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀?”

8 Jésù dáhùn pé, “Mósè yọ̀ǹda kí ẹ kọ aya yín sílẹ̀ nítorí ọkàn yín le. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ láti àtètèkọ́ṣe.

9 Mo sọ èyí fún yín pé, ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, tí ó sì fẹ́ òmíràn, ó ṣe panṣágà.”

10 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Bí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí láàrin ọkọ àti aya, kó ṣààfààní fún wa láti gbé ìyàwó.”

11 Jésù dáhùn pé, “Gbogbo ènìyàn kọ́ ló lé gba ọ̀rọ̀ yìí, bí kò ṣe iye àwọn tí a ti fún.

12 Àwọn mìíràn jẹ́ akúra nítorí bẹ́ẹ̀ nía bí wọn, àwọn mìíràn ń bẹ tí ènìyàn sọ wọn di bẹ́ẹ̀; àwọn mìíràn kọ̀ láti gbé ìyàwó nítorí ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá lè gbà á kí ó gbà á.”

Àwọn Ọmọdé àti Jésù

13 Lẹ́yìn náà a sì gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ wá sọ́dọ̀ Jésù, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì gbàdúrà fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí.

14 Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun, nítorí irú wọn ni ìjọba ọ̀run.”

15 Lẹ́yìn náà, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì kúrò níbẹ̀.

Ọdọ́mọkùnrin Ọlọ́rọ̀

16 Ẹnì kan sì wá ó bí Jésù pé, “Olùkọ́, ohun rere wo ni èmi yóò ṣe kí n tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?”

17 Jésù dá a lóhùn pé, “È é ṣe tí ìwọ fi ń béèrè nípa ohun rere lọ́wọ́ mi. Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà tí í ṣe Ẹni rere. Bí ìwọ bá fẹ́ dé ibi ìyè, pa àwọn òfin mọ́.”

18 Ọkùnrin náà béèrè pé, “Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí?” Jésù dáhùn pé, “ ‘Má ṣe pànìyàn, má ṣe ṣe panṣágà, má ṣe jalè, má ṣe ìjẹ̀rìí èké,

19 bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. Kí o sì fẹ́ aládúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ”

20 Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi mo ní láti ṣe?”

21 Jésù wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.”

22 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

23 Nígbà náà, ní Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.”

24 Mo tún wí fún yín pé, “Ó rọrùn fún ràkúnmí láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.”

25 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ èyí, ẹnu sì yà wọn gidigidi, wọ́n béèrè pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha le là?”

26 Jésù sì tẹjú mọ́ wọn, ó wí pé, “Bí o bá jẹ́ ti ènìyàn ni, eléyìí sòro. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ti Ọlọ́run ni, ohun gbogbo ni ṣíṣe.”

27 Pétérù sì wí fún un pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tẹ̀lé Ọ. Kí ni yóò jẹ́ èrè wa?”

28 Jésù dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ‘Nígbà ìsọdọ̀tun ohun gbogbo, nígbà tí Ọmọ-Ènìyàn yóò jókòó lórí ìtẹ̀ tí ó lógo, dájúdájú, ẹ̀yin ọmọ-ẹ̀yìn mi yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ méjìlá láti ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.

29 Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ilé tàbí arákùnrin tàbí arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ, tàbí ohun ìní rẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mí, yóò gba ọgọọgọ́rùn-ún èrè rẹ̀ láyé, wọn ó sì tún jogún ìyè àìnípẹ̀kun.

30 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ṣíwájú nísinsìn yìí ni yóò kẹ́yìn, àwọn tí ó kẹ́yìn ni yóò sì ṣíwájú.’

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28