1 Jésù bọ́ sínú ọkọ̀, ó sì rékọjá òdo lọ sí ìlú abínibí rẹ̀
2 Àwọn ọkùnrin kan gbé arọ kan tọ̀ ọ́ wá lórí ẹní rẹ̀. Nígbà tí Jésù rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ tújúká, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
3 Nígbà yìí ni àwọn olùkọ́ òfin wí fún ara wọn pé, “Ọkùnrin yìí ń sọ̀rọ̀-òdì!”
4 Jésù sì mọ̀ èrò inú wọn, ó wí pé, “Nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe ń ro búburú nínú yín?
5 Èwo ni ó rọrùn jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ;’ tàbí wí pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn?’
6 Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì ni.” Ó sì wí fún arọ náà pé, “Dìde, sì gbé ẹní rẹ, kí o sì máa lọ ilé rẹ.”
7 Ọkùnrin náà sì dìde, ó sì lọ ilé rẹ̀.
8 Nígbà tí ìjọ ènìyàn rí í ẹnu sì yà wọ́n, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, ti ó fi irú agbára báyìí fún ènìyàn.
9 Bí Jésù sì ti ń rékọjá láti ibẹ̀ lọ, o rí ọkùnrun kan ti à ń pè ní Mátíù, ó jókòó ní ibùdó àwọn agbowó-òde, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn,” Mátíù sì dìde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
10 Ó sì ṣe, bí Jésù tí jókòó ti ó ń jẹun nínú ilé Mátíù, sì kíyèsí i, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-òde àti “ẹlẹ́sẹ̀” wá, wọ́n sì bá a jẹun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
11 Nígbà tí àwọn Farisí sì rí i, wọ́n wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “ ‘Èé ṣe’ tí Olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó-òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ̀ jẹun pọ̀?”
12 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù gbọ́ èyí, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọ́n le kò wá oníṣègùn bí kò ṣe àwọn tí ara wọn kò dá.
13 Ṣùgbọ́n ẹ lọ kọ́ bí a ti mọ̀ èyí sí: ‘Àánú ni èmi ń fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;’ nítorí èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́sẹ̀.”
14 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù tọ̀ ọ́ wá láti béèrè wí pé, “Èé ṣe tí àwa àti àwọn Farisí fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?”
15 Jésù sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ilé ìyàwó ha le máa sọ̀fọ̀, nígbà tí ọkọ ìyàwó ń bẹ lọ́dọ̀ wọn? Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó lọ́wọ́ wọn; nígbà náà ni wọn yóò gbààwẹ̀.
16 “Kò sí ẹni tí í fi ìrépé aṣọ tutun lẹ ògbólògbó ẹ̀wù; nítorí èyí tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò ya ní ojú lílẹ̀, aṣọ náà yóò sì ya púpọ̀ sì i ju ti ìṣáájú lọ.
17 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí fi ọtí titun sínú ògbólògbó ìgò-awọ; bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgò-àwọ yóò bẹ́, ọtí á sì tú jáde, ìgò-àwọ á sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n ọtí titun ni wọn í fi sínú ìgò-àwọ tuntun àwọn méjèèjì a ṣì ṣe dédé.”
18 Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, kíyèsí i, ìjòyè kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ wí pé, “Ọmọbìnrin mi kú nísinsìn yìí, ṣùgbọ́n wá fi ọwọ́ rẹ̀ lé e, òun yóò sì yè.”
19 Jésù dìde ó sì bá a lọ àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
20 Ṣì kíyèsí i, obìnrin kan ti ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ ní ọdún méjìlá, ó wá lẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀.
21 Nítorí ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Bí mo bá sáà le fi ọwọ́ kan ìsẹ́tí aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.”
22 Nígbà tí Jésù sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, “Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dà.” A sì mú obìnrin náà lára dà ni wákàtí kan náà.
23 Nígbà tí Jésù sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afọnfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń paríwó.
24 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ; nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà.
25 Ṣùgbọ́n nígbà tí a ti àwọn ènìyàn jáde, ó wọ ilé, ó sì fà ọmọbìnrin náà ní ọwọ́ sókè; bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin náà sì dìde.
26 Òkìkí èyí sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.
27 Nígbà tí Jésù sì jáde níbẹ̀, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n ń kígbe sókè wí pé, “Ṣàánú fún wa, ìwọ ọmọ Dáfídì.”
28 Nígbà tí ó sì wọ̀ ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ wá, Jésù bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ pé mo le ṣe èyí?”Wọn sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ìwọ lè ṣe é.”
29 Ó sì fi ọwọ́ bà wọ́n ní ojú, ó wí pé, “Kí ó rí fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.”
30 Ojú wọn sì là; Jésù sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi, wí pé, “Kíyèsí i, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kan ki o mọ̀ nípa èyí.”
31 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n lọ, wọ́n ròyìn rẹ̀ yí gbogbo ìlú náà ká.
32 Bí wọ́n tí ń jáde lọ, wò ó wọ́n mú ọkùnrin odi kan tí ó ní ẹ̀mí-èṣù tọ Jesu wá.
33 Nígbà tí a lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin tí ó ya odi sì fọhùn. Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, wọ́n wí pé, “A kò rí irú èyí rí ní Ísírẹ́lì.”
34 Ṣùgbọ́n àwọn Farisí wí pé, “Agbára olórí àwọn ẹ̀mí-èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí-èṣù jáde.”
35 Jésù sì rìn yí gbogbo ìlú ńlá àti ìletò ká, ó ń kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn, ó sì ń wàásù ìyìn rere ìjọba, ó sì ń ṣe ìwòsàn àrùn àti gbogbo àìsàn ní ara àwọn ènìyàn.
36 Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àánú wọn ṣe é, nítorí àárẹ̀ mú wọn, wọn kò sì rí ìrànlọ́wọ́, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.
37 Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni ìkórè pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan
38 Nítorí náà, ẹ gbàdúrà sí Olúwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.”