Mátíù 20 BMY

Òwe Àwọn Òṣìṣẹ́ Nínú Ọgbà Àjàrà

1 “Nítorí ìjọba ọ̀run dàbí ọkùnrin tí ó jẹ́ baálé kan, tí ó jí jáde lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, tí ó gba àwọn alágbàṣe sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.

2 Òun pinnu láti san dínárì kan fún iṣẹ́ òòjọ́ kan. Lẹ́yìn èyí ó sì rán wọn lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.

3 “Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà.

4 Ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin pàápàá, ẹ lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà mi, bí ó bá sì di òpin ọjọ́, èmi yóò san iye ti ó bá yẹ fún yín.’

5 Wọ́n sì lọ“Ó tún jáde lọ́sàn-án ní nǹkan bí wákàtí kẹfa àti wákàtí kẹṣàn-án, ó tún ṣe bákan náà.

6 Lọ́jọ́ kan náà ní wákàtí kọkànlá ọjọ́, ó tún jáde sí àárin ìlú, ó sì rí àwọn aláìríṣẹ́ mìíràn tí wọ́n dúró. Ó bi wọ́n pé, ‘È é ṣe tí ẹ̀yin kì í ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́?’

7 “Wọ́n sì dáhùn pé, ‘Nítorí pé kò sí ẹni tí yóò fún wa ní iṣẹ́ ṣe.’ Ó tún sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ jáde lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú nínú ọgbà àjàrà mi.’

8 “Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà sọ fún aṣojú rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òsiṣẹ́ náà, kí ó san owó iṣẹ́ wọn fún wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ẹni ìkẹyìn lọ sí ti ìṣáájú.’

9 “Nígbà tí àwọn ti a pè ní wákàtí kọkànlá ọjọ́ dé, ẹnì kọ̀ọ̀kan gba owó dínárì kan.

10 Nígbà tí àwọn tí a gbà ṣíṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́ fẹ́ gba owó ti wọn, èrò wọn ni pé àwọn yóò gba jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan.

11 Bí wọ́n ti ń gbà á, wọ́n ń kùn sí onílẹ̀ náà,

12 Pé, ‘Wákàtí kan péré ni àwọn tí a gbà kẹ́yìn fi ṣiṣẹ́, ìwọ sì san iye kan náà fún wọn àti àwa náà ti a fi gbogbo ọjọ́ ṣiṣẹ́ nínú oòrùn gan-gan.’

13 “Ṣùgbọ́n ó dá ọ̀kan nínú wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀rẹ́, kò sí aburú nínú nǹkan tí èmi ṣe sí yín. Kì í ha ṣe pé ẹ̀yin gbà láti ṣiṣẹ́ fún owó dínárì kan.

14 Ó ní, Gba èyí tíí ṣé tìrẹ, ki ó sì máa lọ. Èmi fẹ́ láti fún ẹni ìkẹ̀yìn gẹ́gẹ́ bí mo ti fi fún ọ.

15 Àbí ó lòdì sí òfin pé kí èmi fún ẹnikẹ́ni ní owó mi bí mo bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni ìdí tí ìwọ ní láti bínú nítorí èmi ṣe ohun rere?’

16 “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ìkẹyìn yóò di ẹni ìṣáájú, ẹni ìṣáájú yóò sì di ẹni ìkẹyìn.”

Jésù Tún sọ Sọtẹ́lẹ̀ nípa Ikú Rẹ̀

17 Bí Jésù ti ń gòkè lọ sí Jerúsálémù, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí apá kan ó sì wí pé,

18 “Wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù. Ó sọ fún wọn pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá mi lẹ́bi ikú.

19 Wọn yóò sì lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti nàa án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde.”

Ẹbẹ̀ Ìyá

20 Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sébédè bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jésù, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojú rere rẹ̀.

21 Jésù béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”Ó sì dáhùn pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ?”

22 Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn ó sì wí pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀yin ń béèrè, ẹ̀yin ha le mu nínú aago tí èmi ó mu?”Wọ́n dáhùn pé, “Àwa lè mu ún.”

23 Jésù sì wí fún wọn pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin yóò mu nínú aago mi, ṣùgbọ́n èmi kò ní àṣẹ láti sọ irú ènìyàn tí yóò jòkòó ní apá ọ̀tún tàbí apá òsì. Baba mi ti pèsè àyè wọ́n-ọn-nì sílẹ̀ fún kìkì àwọn tí ó yàn.”

24 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàà ìyókù sì gbọ́ èyí, wọ́n bínú sí àwọn arákùnrin méjì yìí.

25 Ṣùgbọ́n Jésù pé wọ́n papọ̀, ó wí pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin mọ̀ pé àwọn ọba aláìkọlà a máa lo agbára lórí wọn, àwọn ẹni ńlá láàrin wọn a sì máa fi ọlá tẹrí àwọn tí ó wà lábẹ́ wọn ba.

26 Ṣùgbọ́n èyí yàtọ̀ láàrin yín. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó bá ń fẹ́ ṣe olórí láàrin yín, ní láti ṣe bí ìránṣẹ́ fún yín ni,

27 Àti ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe olórí nínú yín, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣe Ọmọ-ọ̀dọ̀ yin.

28 Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ-Ènìyàn kò ṣe wá sí ayé, kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún yín, àti láti fi ẹ̀mí rẹ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”

Afọ́jú Méjì Ríran

29 Bí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń fi ìlú Jẹ́ríkò sílẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì wọ́ tẹ̀lé e lẹ́yìn.

30 Àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì sì jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, nígbà tí wọ́n sí gbọ́ pé Jésù ń kọjá lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí kígbe pé, “Olúwa, Ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún wa!”

31 Àwọn ènìyàn sí bá wọn wí pé kí wọn dákẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n kígbe sóke sí i. “Olúwa, ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún wa!”

32 Jésù dúró lójú ọ̀nà, ó sì pè wọ́n pé, Ó béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin fẹ́ kí èmi ṣe fún yín?”

33 Wọ́n dáhùn pé, “Olúwa, àwa fẹ́ kí a ríran.”

34 Àánú wọn sì ṣe Jésù, ó fi ọwọ́ kan ojú wọn. Lójú kan náà, wọ́n sì ríran, wọ́n sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28