Mátíù 11 BMY

Jésù àti Jòhánù onítẹ̀bọmi

1 Lẹ́yìn ìgbà tí Jésù sì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá, ó ti ibẹ̀ rékọjá láti máa kọ́ni àti láti máa wàásù ní àwọn ìlú Gálílì gbogbo.

2 Nígbà tí Jòhánù gbọ́ ohun tí Kírísítì ṣe nínú ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

3 láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣe ìwọ ni ẹni tó ń bọ̀ wá tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”

4 Jésù dáhùn ó wí pé, “Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Jòhánù ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí.

5 Àwọn afójú ń ríran, àwọn amúkùn ún rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ wọn, àwọn adití ń gbọ́ràn, a ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń wàásù ìyìn rere fún àwọn òtòsì.

6 Alábùkún fún ni ẹni tí kò rí ohun ìkọ̀sẹ̀ nípa mi.”

7 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù ti lọ tán, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ti Jòhánù: “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò ní aginijù? Iféfé tí afẹ́fẹ́ ń mi?

8 Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí ni ẹ̀yin lọ òde lọ í wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ni aṣọ dáradára? Rárá àwọn ti ó wọ aṣọ dáradára wà ní ààfin ọba.

9 Àní kí ní ẹ jáde láti lọ wò? Wòlíì? Bẹ́ẹ̀ ni, mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ.”

10 Èyí ni ẹni tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:“ ‘Èmi yóò rán ìránṣẹ́ mi ṣíwájú rẹ,ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’

11 Lóòótọ̀ ni mó wí fún yín, nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí ẹni tí ó tí í dìde tí ó ga ju Jòhánù onítẹ̀bọmi lọ, síbẹ̀ ẹni tí ó kéré jù ní ìjọba ọ̀run ni ó pọ̀ jù ú lọ.

12 Láti ìgbà ọjọ́ Jòhánù onítẹ̀bọmi títí di àkókò yìí ni ìjọba ọ̀run ti di àfagbárawọ̀, àwọn alágbára ló ń fi ipá gbà á.

13 Nítorí náà gbogbo òfin àti wòlíì ni ó wí tẹ́lẹ̀ kí Jòhánù kí ó tó dé.

14 Bí ẹ̀yin yóò bá gbà á, èyí ni Èlíjà tó ń bọ̀ wá.

15 Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́

16 “Kí ni èmi ìbá fi ìran yìí wé? Ó dàbí àwọn ọmọ kékéré tí ń jókòó ní ọjà tí wọ́n sì ń ké pe àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn:

17 “ ‘Àwa ń fun fèrè fún yín,ẹ̀yin kò jó;àwa kọrin ọ̀fọ̀ẹ̀yin kò káàánú.’

18 Nítorí Jòhánù wá kò bá a yín jẹ bẹ́ẹ̀ ni kò mu, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù.’

19 Ọmọ ènìyàn wá bá a yín jẹun, ó sì bá yin mu, wọ́n wí pé, ọ̀jẹun àti ọ̀mùtì; ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ̀, ṣùgbọ́n a dá ọgbọ́n láre nípa ìṣe rẹ̀.”

Ègbé ni fún àwọn ìlú tí kò Ronúpìwàdà

20 Nígbà náà ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìlú tí ó ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ wí, nítorí wọn kò ìronúpìwàdà.

21 Ó wí pé, “Ègbé ni fún ìwọ Kórásínì, ègbé ni fún ìwọ Bẹtisáídà! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a se nínú yín ní Tírè àti Sídónì, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà tipẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.

22 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Tírè àti Sídónì ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín.

23 Àti ìwọ Kápánámù, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run?, Rárá a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú. Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sódómù, òun ìbá wà títí di òní.

24 Lóòótọ́ yóò sàn fún ilẹ̀ Sódómù ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ìwọ lọ.”

Ìsinmi fún Aláàárẹ̀

25 Nígbà náà ni Jésù wí pé, “Mo yìn ọ Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, nítorí ìwọ ti fi òtítọ́ yìí pamọ́ fún àwọn tó jẹ́ ọlọgbọ́n àti amòyé, Ìwọ sì ti fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.

26 Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí ó wù ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

27 “Ohun gbogbo ni Baba mi ti fi sí ìkáwọ́ mi. Kò sí ẹni tí ó mọ ọmọ bí kò se Baba, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ Baba, bí kò ṣe ọmọ, àti àwọn tí ọmọ yan láti fi ara hàn fún.

28 “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wí wúwo lé lórí, èmi yóò sì fún yín ní ìsinmi.

29 Ẹ gbé àjàgà mi wọ̀. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi nítorí onínútútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi, ẹ̀yin yóò sì fi ìsinmi fún ọkàn yín.

30 Nítorí àjàgà mi rọrùn ẹrù mi sì fúyẹ́.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28