13 Sèrérúbábélì ni baba Ábíúdì;Ábíúdì ni baba Élíákímù;Élíákímù ni baba Ásórì;
14 Ásórì ni baba Sádókù;Sádókù ni baba Ákímù;Ákímù ni baba Élíúdì;
15 Élíúdì ni baba Élíásárì;Élíásárì ni baba Mátítánì;Mátítánì ni baba Jákọ́bù;
16 Jákọ́bù ni baba Jósẹ́fù, ẹni tí ń ṣe ọkọ Màríà, ìyá Jésù, ẹni tí í ṣe Kírísítì.
17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́ ìran mẹ́rìnlá láti orí Ábúráhámù dé orí Dáfídì, ìran mẹ́rìnlà á láti orí Dáfídì títí dé ìkólọ sí Bábílónì, àti ìran mẹ́rìnlà láti ìkólọ títí dé orí Kírísítì.
18 Bí a ṣe bí Jésù nì yìí: Ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrin Màríà ìyá rẹ̀ àti Jósẹ́fù, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́.
19 Nítorí Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòótọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójú tì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.