1 Jésù sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí ọ̀dọ̀; ó fún wọn ní àṣẹ láti lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde àti láti ṣe ìwòsàn àrùn àti àìsàn gbogbo.
2 Orúkọ àwọn àpósítélì méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí: ẹni àkọ́kọ́ ni Símónì ẹni ti a ń pè ni Pétérù àti arákùnrin rẹ̀ Ańdérù, Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti arákùnrin rẹ̀ Jòhánù.
3 Fílípì àti Bátólómíù; Tómásì àti Mátíù agbowó òde; Jákọ́bù ọmọ Álíféù àti Tádéù;
4 Símónì ọmọ ẹgbẹ́ Sílíọ́tì, Júdásì Ísíkáríọ́tù, ẹni tí ó da Jésù.
5 Jésù ran àwọn méjèèjìla yìí jáde, pẹ̀lú àṣẹ báyìí pé: “Ẹ má ṣe lọ sì àárín àwọn aláìkọlà tàbí wọ̀ èyíkèyìí ìlú àwọn ará Samáríà