10 Ẹ má ṣe mú àpo fún ìrìnàjò yín, kí ẹ má ṣe mú ẹ̀wù méjì, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá; oúnjẹ oníṣẹ́ yẹ fún un.
11 “Ìlúkílùú tàbí ìletòkíletò tí ẹ̀yin bá wọ̀, ẹ wá ẹni ti ó bá yẹ níbẹ̀ rí, níbẹ̀ ni kí ẹ sì gbé nínú ilé rẹ̀ títítí ẹ̀yin yóò fi kúrò níbẹ̀.
12 Nígbà tí ẹ̀yin bá sì wọ ilé kan, ẹ kí i wọn.
13 Bí ilé náa bá sì yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó bà sórí rẹ̀; ṣùgbọ́n bí kò bá yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó padà sọ́dọ̀ yín.
14 Bí ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tàbí tí kò gba ọ̀rọ̀ yín, ẹ gbọn eruku ẹ̀ṣẹ̀ yín sílẹ̀ tí ẹ bá ń kúrò ní ilé tàbí ìlú náà.
15 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò sàn fún ìlú Sódómù àti Gòmórà ní ọjọ́ ìdájọ́ ju àwọn ìlú náà lọ.
16 Mò ń rán yín lọ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàrin ìkookò. Nítorí náà, kí ẹ ní ìṣọ́ra bí ejò, kí ẹ sì ṣe onírẹ̀lẹ̀ bí àdàbà.