19 Nígbà tí wọ́n bá mú yín, ẹ má ṣe ṣàníyàn ohun tí ẹ ó sọ tàbí bí ẹ ó ṣe sọ ọ́. Ní ojú kan náà ni a ó fi ohun tí ẹ̀yin yóò sọ fún yín,
20 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ó sọ ọ́, bí kò ṣe Ẹ̀mí Baba yín tí ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín.
21 “Ọmọ-ìyá méjì yóò ṣe ikú pa ara wọ́n. Baba yóò fi àwọn ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóò sọ̀tẹ̀ sí òbí wọn, wọn yóò sì mú kí a pa wọ́n.”
22 Gbogbo ènìyàn yóò sì kórìíra yín nítorí mi, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó bá dúró ṣinṣin dé òpin ni a ó gbàlà.
23 Nígbà tí wọn bá ṣe inúnibíni sì i yín ní ìlú kan, ẹ sá lọ sì ìlú kejì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin kò tì í le la gbogbo ìlú Ísírẹ́lì já tán kí Ọmọ Ènìyàn tó dé.
24 “Akẹ́kọ̀ọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ-ọ̀dọ̀ kì í ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.
25 Ó tọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láti dà bí olùkọ́ rẹ̀ àti fún ọmọ-ọ̀dọ̀ láti rí bí ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá pe baálé ilé ní Béélísébúbù, mélòó mélòó ni ti àwọn ènìyàn ilé rẹ̀!