21 “Ọmọ-ìyá méjì yóò ṣe ikú pa ara wọ́n. Baba yóò fi àwọn ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóò sọ̀tẹ̀ sí òbí wọn, wọn yóò sì mú kí a pa wọ́n.”
22 Gbogbo ènìyàn yóò sì kórìíra yín nítorí mi, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó bá dúró ṣinṣin dé òpin ni a ó gbàlà.
23 Nígbà tí wọn bá ṣe inúnibíni sì i yín ní ìlú kan, ẹ sá lọ sì ìlú kejì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin kò tì í le la gbogbo ìlú Ísírẹ́lì já tán kí Ọmọ Ènìyàn tó dé.
24 “Akẹ́kọ̀ọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ-ọ̀dọ̀ kì í ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.
25 Ó tọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láti dà bí olùkọ́ rẹ̀ àti fún ọmọ-ọ̀dọ̀ láti rí bí ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá pe baálé ilé ní Béélísébúbù, mélòó mélòó ni ti àwọn ènìyàn ilé rẹ̀!
26 “Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí kò sí ohun to bò tí kò níí fara hàn, tàbí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ tí a kò ní mọ̀ ni gbangba.
27 Ohun tí mo bá wí fún yín ní òkùnkùn, òun ni kí ẹ sọ ní ìmọ́lẹ̀. Èyí tí mo sọ kẹ́lẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì etí yín ni kí ẹ kéde rẹ́ lórí òrùlé.