32 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú ènìyàn, òun náà ni èmi yóò jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run.
33 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mí ní níwájú àwọn ènìyàn, òun náà ni èmi náà yóò sọ wí pé n kò mọ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run.
34 “Ẹ má ṣe rò pé mo mú àlàáfíà wá sí ayé, Èmi kò mú àlàáfíà wá bí kò ṣe idà.
35 Nítorí èmi wá láti“ ‘ọmọkùnrin ní ipa sí bàbá rẹ̀,ọmọbìnrin ní ipa sí ìyá rẹ̀,àti aya ọmọ sí ìyakọ rẹ̀…
36 Ará ilé ènìyàn ni yóò sì máa ṣe ọ̀tá rẹ̀.’
37 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn bàbá rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ jù mí lọ kò yẹ ní tèmi, ẹnikẹ́ni tí ó ba fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin jù mí lọ kò yẹ ní tèmi;
38 Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó tẹ̀ lé mi kò yẹ ní tèmi.