37 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn bàbá rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ jù mí lọ kò yẹ ní tèmi, ẹnikẹ́ni tí ó ba fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin jù mí lọ kò yẹ ní tèmi;
38 Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó tẹ̀ lé mi kò yẹ ní tèmi.
39 Ẹni tí ó bá rí ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i.
40 “Ẹni tí ó bá gbà yín, ó gbà mí, ẹni tí ó bá sì gbà mí gba ẹni tí ó rán mi.
41 Ẹni tí ó ba gba wòlíì, nítorí pé ó jẹ́ wòlíì yóò jẹ èrè wòlíì, ẹni tí ó bá sì gba olódodo nítorí ti ó jẹ́ ènìyàn olódodo, yóò jẹ èrè olódodo.
42 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ago omi tútú fún ọ̀kan nínú àwọn onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mu nítorí tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, ọ̀títọ́ ni mo wí fún yín, kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”