5 Jésù ran àwọn méjèèjìla yìí jáde, pẹ̀lú àṣẹ báyìí pé: “Ẹ má ṣe lọ sì àárín àwọn aláìkọlà tàbí wọ̀ èyíkèyìí ìlú àwọn ará Samáríà
6 Ẹ kúkú tọ̀ àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí ó nù lọ.
7 Bí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ máa wàásù yìí wí pé: ‘Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.’
8 Ẹ máa ṣe ìwòṣan fún àwọn aláìsàn, ẹ si jí àwọn okú dìde, ẹ sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, kí ẹ sì máa lé àwọn ẹ̀mí-èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbàá, ọ̀fẹ́ ni kú ẹ fi fún ni.
9 Ẹ má ṣe mú wúrà tàbí fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìgbànú yín;
10 Ẹ má ṣe mú àpo fún ìrìnàjò yín, kí ẹ má ṣe mú ẹ̀wù méjì, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá; oúnjẹ oníṣẹ́ yẹ fún un.
11 “Ìlúkílùú tàbí ìletòkíletò tí ẹ̀yin bá wọ̀, ẹ wá ẹni ti ó bá yẹ níbẹ̀ rí, níbẹ̀ ni kí ẹ sì gbé nínú ilé rẹ̀ títítí ẹ̀yin yóò fi kúrò níbẹ̀.