12 Láti ìgbà ọjọ́ Jòhánù onítẹ̀bọmi títí di àkókò yìí ni ìjọba ọ̀run ti di àfagbárawọ̀, àwọn alágbára ló ń fi ipá gbà á.
13 Nítorí náà gbogbo òfin àti wòlíì ni ó wí tẹ́lẹ̀ kí Jòhánù kí ó tó dé.
14 Bí ẹ̀yin yóò bá gbà á, èyí ni Èlíjà tó ń bọ̀ wá.
15 Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́
16 “Kí ni èmi ìbá fi ìran yìí wé? Ó dàbí àwọn ọmọ kékéré tí ń jókòó ní ọjà tí wọ́n sì ń ké pe àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn:
17 “ ‘Àwa ń fun fèrè fún yín,ẹ̀yin kò jó;àwa kọrin ọ̀fọ̀ẹ̀yin kò káàánú.’
18 Nítorí Jòhánù wá kò bá a yín jẹ bẹ́ẹ̀ ni kò mu, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù.’