21 Ó wí pé, “Ègbé ni fún ìwọ Kórásínì, ègbé ni fún ìwọ Bẹtisáídà! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a se nínú yín ní Tírè àti Sídónì, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà tipẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.
22 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Tírè àti Sídónì ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín.
23 Àti ìwọ Kápánámù, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run?, Rárá a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú. Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sódómù, òun ìbá wà títí di òní.
24 Lóòótọ́ yóò sàn fún ilẹ̀ Sódómù ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ìwọ lọ.”
25 Nígbà náà ni Jésù wí pé, “Mo yìn ọ Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, nítorí ìwọ ti fi òtítọ́ yìí pamọ́ fún àwọn tó jẹ́ ọlọgbọ́n àti amòyé, Ìwọ sì ti fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.
26 Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí ó wù ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
27 “Ohun gbogbo ni Baba mi ti fi sí ìkáwọ́ mi. Kò sí ẹni tí ó mọ ọmọ bí kò se Baba, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ Baba, bí kò ṣe ọmọ, àti àwọn tí ọmọ yan láti fi ara hàn fún.