7 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù ti lọ tán, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ti Jòhánù: “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò ní aginijù? Iféfé tí afẹ́fẹ́ ń mi?
8 Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí ni ẹ̀yin lọ òde lọ í wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ni aṣọ dáradára? Rárá àwọn ti ó wọ aṣọ dáradára wà ní ààfin ọba.
9 Àní kí ní ẹ jáde láti lọ wò? Wòlíì? Bẹ́ẹ̀ ni, mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ.”
10 Èyí ni ẹni tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:“ ‘Èmi yóò rán ìránṣẹ́ mi ṣíwájú rẹ,ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’
11 Lóòótọ̀ ni mó wí fún yín, nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí ẹni tí ó tí í dìde tí ó ga ju Jòhánù onítẹ̀bọmi lọ, síbẹ̀ ẹni tí ó kéré jù ní ìjọba ọ̀run ni ó pọ̀ jù ú lọ.
12 Láti ìgbà ọjọ́ Jòhánù onítẹ̀bọmi títí di àkókò yìí ni ìjọba ọ̀run ti di àfagbárawọ̀, àwọn alágbára ló ń fi ipá gbà á.
13 Nítorí náà gbogbo òfin àti wòlíì ni ó wí tẹ́lẹ̀ kí Jòhánù kí ó tó dé.