45 Nígbà náà ni ẹ̀mí ẹ̀ṣù náà yóò wá ẹ̀mí méje mìíràn tí ó burú ju òun lọ. Gbogbo wọn yóò sì wá sí inú rẹ̀, wọn yóò máa gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà a sì burú ju ti ìṣáájú lọ; Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí fún ìran búburú yìí pẹ̀lú.”
46 Bí Jésù ti ṣe ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wà lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀.
47 Nígbà náà ni ẹnì kan wí fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró dè ọ́ lóde wọ́n ń fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”
48 Ó sì fún ni èsì pé, “Ta ni ìyá mi? Ta ni àwọn arákùnrin mi?”
49 Ó nawọ́ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí pé, “Wò ó, ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni wọ̀nyí.”
50 Nítorí náà, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”