13 Ìdí nì yìí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀:“Ní ti rírí, wọn kò rí;ní ti gbígbọ́ wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sì yé wọn.
14 Sí ara wọn ni a ti mú àṣọtẹ́lẹ̀ wòlíì Àìsáyà ṣẹ:“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́ ṣùgbọn kì yóò sì yé yín;ní rírí ẹ̀yin yóò rí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò sì mòye.
15 Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́etí wọn sì wúwo láti gbọ́ojú wọn ni wọ́n sì dìnítorí kí àwọn má ba à fi ojú wọn ríkí wọ́n má ba à fi ètí wọn gbọ́kí wọn má ba à fi àyà wọn mọ̀ òge,kí wọn má ba à yí padà, kí èmi ba à le mú wọn lára dá.’
16 Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ojú yín, nítorí wọ́n ríran, àti fún etí yín, nítorí ti wọ́n gbọ́.
17 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti ènìyàn Ọlọ́run ti fẹ́ rí ohun tí ẹ̀yin ti rí, ki wọ́n sì gbọ́ ohun tí ẹ ti gbọ́, ṣùgbọ́n kò ṣe é ṣe fún wọn.
18 “Nítorí náà, ẹ fi etí sí ohun tí òwe afúnrúgbìn túmọ̀ sí:
19 Nigbà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìjọba ọ̀run ṣùgbọ́n tí kò yé e, lẹ́yìn náà èṣù á wá, a sì gba èyí tí a fún sí ọkàn rẹ̀ kúrò. Èyí ni irúgbìn ti a fún sí ẹ̀bá ọ̀nà.