5 Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ orí àpáta, níbi ti kò sí erùpẹ̀ púpọ̀. Àwọn irúgbìn náà sì dàgbà sókè kíákíá, nítorí erùpẹ̀ kò pọ̀ lórí wọn.
6 Ṣùgbọ́n nígbà tí òòrùn gòkè, oòrùn gbígbóná jó wọn, gbogbo wọ sì rọ, wọ́n kú nítorí wọn kò ni gbòǹgbò.
7 Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sí àárin ẹ̀gún, ẹ̀gún sì dàgbà, ó sì fún wọn pa.
8 Ṣùgbọ́n díẹ̀ tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rún, òmiràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, ni ìlọ́po èyí ó ti gbìn.
9 Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́.”
10 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bí i pé, “Èé ṣe tí ìwọ ń fi òwe bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀?”
11 Ó sì da wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a ti fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wọn.