5 Nígbà tí wọ́n dé apá kejì adágún, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sàkíyèsí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà kankan lọ́wọ́.
6 Jésù sì kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyè sára, ẹ sì ṣọ́ra, ní ti ìwúkàrà àwọn Farisí àti àwọn Sadusí.”
7 Wọ́n ń sọ eléyìí ni àárin ara wọn nítorí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà lọ́wọ́.
8 Nígbà tí ó gbọ́ ohun ti wọ́n ń sọ, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré, èé ṣe tí ẹ̀yin ń dààmú ara yín pé ẹ̀yin kò mú oúnjẹ lọ́wọ́?
9 Tàbí ọ̀rọ̀ kò yé yín di ìsinsìn yìí? Ẹ̀yin kò rántí pé mo bọ́ ẹgbẹẹ́dọ́gbọ́n (5,000) ènìyàn pẹ̀lú ìsù búrẹ́dì márùn-ún àti iye agbọ̀n tí ẹ kó jọ bí àjẹkù?
10 Ẹ kò sì tún rántí ìsù méje tí mo fi bọ́ ẹgbààjì (4,000) ènìyàn àti iye àjẹkù tí ẹ kó jọ?
11 È é ha ṣe tí kò fi yé yín pé èmi kò sọ̀rọ̀ nípa ti búrẹ́dì? Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo wí fún yín, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti ti Sadusí.”