Mátíù 18:7-13 BMY

7 “Ègbé ni fún ayé nítorí gbogbo ohun ìkọ̀sẹ̀ rẹ̀! Ohun ìkọ̀sẹ̀ kò le ṣe kó má wà, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípaṣẹ̀ ẹni tí ìkọ̀sẹ̀ náà ti wá!

8 Nítorí náà, bí ọwọ́ tàbí ẹṣẹ̀ rẹ yóò bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀, gé e kúrò, kí o sì jù ú nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run ní akéwọ́ tàbí akésẹ̀ ju pé kí o ni ọwọ́ méjì àti ẹsẹ̀ méjì ki a sì sọ ọ́ sínú iná ayérayé.

9 Bí ojú rẹ yóò bá sì mú kí o dẹ́sẹ̀, yọ ọ́ kúrò kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run pẹ̀lú ojú kan, ju pé kí o ní ojú méjì, kí a sì jù ọ́ sí iná ọ̀run àpádì.

10 “Ẹ rí i pé ẹ kò fi ojú bẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, nígbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run ń láti lọ wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.

11 Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn wá láti gba àwọn tí ó nù là.

12 “Kí ni ẹ̀yin rò? Bí ọkùnrin kan bá ni ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ẹyọ kan nínú wọn sì sọnù, ṣé òun kì yóò fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) ìyókù sílẹ̀ sórí òkè láti lọ wá ẹyọ kan tó nù náà bí?

13 Ǹjẹ́ bí òun bá sì wá á rí i, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé inú rẹ̀ yóò dùn nítorí rẹ̀ ju àwọn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún tí kò nù lọ?