14 Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Éjíbítì,
15 ó sì wà níbẹ̀ títítí Hẹ́rọ́dù fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àṣọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé: “Mo pe ọmọ mi jáde láti Éjíbítì wá.”
16 Nígbà tí Hẹ́rọ̀dù rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà.
17 Nígbà náà ni èyí tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeriemáyà wá sẹ pé:
18 “A gbọ́ ohùn kan ní Rámà,Ohùn réré ẹkún àti ọ̀fọ̀ ńláRákélì ń sọkùn àwọn ọmọ rẹ̀Ó kọ̀ láti gbìpẹ̀nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò sí mọ́.”
19 Lẹ́yìn ikú Hẹ́rọ́dù, ańgẹ́lì Olúwa fara hàn Jósẹ́fù lójú àlá ní Éjíbítì
20 Ó sì wí fún un pé, “Dìde gbé ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ padà sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, nítorí àwọn tí ń wá ọmọ-ọwọ́ náà láti pa ti kú.”