13 Ó wí fún wọn pé, “A sáà ti kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a ó máa pe ilé mi’, ṣùgbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùdó àwọn ọlọ́ṣà.”
14 A sì mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní tẹ̀ḿpìlì, ó sì mú wọ́n láradá
15 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin rí àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá wọ̀nyí, ti wọ́n sì tún ń gbọ́ tí àwọn ọmọdé ń kigbé nínú tẹ́ḿpìlì pé, “Hòsánà fún ọmọ Dáfídì,” inú bí wọn.
16 Wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ ìwọ gbọ́ nǹkan tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń sọ?”Jésù sí dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni,”“Àbí ẹ̀yin kò kà á pé ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ-ọmú,ni a ó ti máa yìn mí’?”
17 Ó sì fi wọ́n sílẹ̀, ó lọ sí Bẹ́tánì. Níbẹ̀ ni ó dúró ní òru náà.
18 Ní òwúrọ̀ bí ó ṣe ń padà sí ìlú, ebi ń pa á.
19 Ó sì ṣàkíyèsí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lẹ́bàá ojú ọ̀nà, ó sì lọ wò ó bóyá àwọn èso wà lórí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹyọ kan, ewé nìkan ni ó wà lórí rẹ̀. Nígbà náà ni ó sì wí fún igi náà pé, “Kí èso má tún so lórí rẹ mọ́.” Lójú kan náà igi ọ̀pọ̀tọ́ náà sì gbẹ.