Mátíù 21:21-27 BMY

21 Jésù wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ̀yin bá lè ní ìgbàgbọ́ láì síyè méjì, nígbà náà ẹ̀yin yóò lè ṣe irú tí a se sí igi ọ̀pọ̀tọ́, Ẹ̀yin yóò lè sọ fún òkè yìí pé, ‘Yí ipò padà sínú òkun,’ yóò sì ríbẹ́ẹ̀.

22 Bí ẹ̀yin bá gbàgbọ́, ẹ̀yin lè rí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè nínú àdúrà gbà.”

23 Jésù wọ tẹ̀ḿpìlì, nígbà tí ó ń kọ́ni, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù tọ̀ ọ́ wá. Wọ́n béèrè pé “nípa àṣẹ wo ni o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí? Ta ni ó sì fún ọ ni àsẹ yìí?”

24 Jésù sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi yóò si bí yin léère ohun kan pàtọ́, bí ẹ̀yin bá lé sọ fún mi, nígbà náà èmi yóò sọ fún yín, àṣẹ tí Èmi fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí.

25 Níbo ni ìtẹ̀bọmi Jóhànù ti wa? Láti ọ̀run wá ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn.”Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé láti ọ̀run wá ni, òun yóò wí fún wa pé, ‘È é ha ti ṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’

26 Ní ìdà kejì, bí àwa bá sì sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ àwa bẹ̀rù ìjọ ènìyàn, nítorí gbogbo wọ́n ka Johanu sí wòlíì.”

27 Nítorí náà wọ́n sì dáhùn pé, “Àwa kò mọ̀.”Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí èyí, èmi kò ní sọ àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín.