1 Jésù tún fi òwe sọ̀rọ̀ fún wọn wí pé:
2 “Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan ti ó múra àṣè ìgbéyàwó ńlá fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin.
3 Ó rán àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti lọ sọ fún àwọn tí a ti pè tẹ́lẹ̀ pé àsìkò ti tó láti wá sí ibi àsè. Ṣùgbọ́n gbogbo wọn kọ̀ láti wá.
4 “Lẹ́yìn náà ó tún rán àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mìíràn pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí mo ti pè wí pé, mo ti se àsè náà tán. A pa màlúù àti ẹran àbọ́pa mi, a ti ṣe ohun gbogbo tán, ẹ wa sí ibi àsè ìgbéyáwó.’
5 “Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó ránṣẹ́ lọ pè kò kán á si. Wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ, ọ̀kan sí ọ̀nà oko rẹ̀, òmíràn sí ibi òwò rẹ̀.”
6 Àwọn ìyókù sì lu àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ta àbùkù fún wọn, wọ́n lù wọ́n pa.