43 Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni dé tí Dáfídì, tí ẹ̀mí ń darí, pè é ní ‘Olúwa’? Nítorí ó wí pé,
44 “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi,“Jòkòó ní ọwọ́ ọ̀tún mitítí tí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀ta rẹsí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.” ’
45 Ǹjẹ́ bí Dáfídì bá pè é ni ‘Olúwa,’ báwo ni òun se lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
46 Kò sí ẹnì kan tí ó lè sọ ọ̀rọ̀ kan ni ìdáhùn, kò tún sí ẹni tí ó tún bí i léèrè ohun kan mọ́ láti ọjọ́ náà mọ́.