1 “Nígbà náà ni ó fi ìjọba ọ̀run wé àwọn wúńdíá mẹ́wàá. Ti wọ́n gbé àtùpa wọn láti lọ pàdé ọkọ ìyàwó.
2 Márùn-ún nínú wọn jẹ́ ọlọgbọ́n, márùn-ún nínú wọn ni wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n.
3 Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n gbé àtùpà wọn ṣùgbọ́n wọn kò mú epo kankan lọ́wọ́.
4 Àwọn ọlọ́gbọ́n mú epo sínú kólòbó dání pẹ̀lú àtùpà wọn.
5 Nígbà tí ọkọ ìyàwó pẹ́, gbogbo wọn tòògbé wọn sì sùn.
6 “Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, igbe ta sókè, ‘Wò ó, ọkọ ìyàwó ń bọ̀, ẹ jáde sóde láti pàdé rẹ̀.’
7 “Nígbà náà ni àwọn wúńdíá sì tají, wọ́n tún àtùpà wọn ṣe.