29 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní a ó fún sí i, yóò sí tún ní sí lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n láti ọwọ́ ẹni tí kò ní ni a ó ti gbà èyí tí ó ní.
30 Nítorí ìdi èyí, gbé aláìlérè ọmọ-ọ̀dọ̀, jù ú sínú òkùnkùn lóde, ibẹ̀ niẹ̀kún òun ìpayínkeke yóò gbé wà.’
31 “Ṣùgbọ́n nígbà ti Ọmọ-Ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo ní ọ̀run.
32 Gbogbo orílẹ̀-èdè ni a ó kó jọ níwájú rẹ̀, òun yóò sì ya àwọn ènìyàn ayé sí ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe é ya àgùntàn kúrò lára àwọn ewúrẹ́.
33 Òun yóò sì fi àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún àti ewúrẹ́ sí ọwọ́ òsì.
34 “Nígbà náà ni Ọba yóò wí fún àwọn tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún fún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè fún yín láti ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ayé.
35 Nítorí ebí pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, òrùngbẹ gbẹ mí, ẹyin sì fún mi ní omi. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì pè mí sínú ilé yín.