7 “Nígbà náà ni àwọn wúńdíá sì tají, wọ́n tún àtùpà wọn ṣe.
8 Àwọn aláìgbọ́n márùn-ún tí kò ní epo rárá bẹ àwọn ọlọgbọ́n pé kí wọn fún àwọn nínú èyí tí wọ́n ní nítorí àtùpà wọn ń kú lọ.
9 “Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n márùn-ún dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ó má baà ṣe aláìtó fún àwa àti ẹ̀yin, ẹ kúkú tọ àwọn tí ń tà á lọ, kí ẹ sì rà fún ara yín.
10 “Ní àsìkò tí wọ́n lọ ra epo tiwọn, ni ọkọ ìyàwó dé. Àwọn wúńdíá tí ó múra tán bá a wọlé sí ibi àṣè ìgbéyàwó, lẹ̀yìn náà, a sì ti ìlẹ̀kùn.
11 “Ní ìkẹyìn ni àwọn wúńdíá márùn-ún ìyókù dé, wọ́n ń wí pé, ‘olúwa, olúwa, sílẹ̀kùn fún wa.’
12 “Ṣùgbọ́n ọkọ ìyàwó dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín èmi kò mọ̀ yín rí.’
13 “Nítorí náà, Ẹ máa ṣọ́nà. Nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí Ọmọ-Ènìyàn yóò dé.