67 Wọ́n tu itọ́ sí i ní ojú. Wọ́n gbá a lẹ́sẹ̀ẹ́. Àwọn ẹlòmíràn sì gbá a lójú.
68 Wọ́n wí pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wa! Ìwọ Kírísítì, Ta ni ẹni tí ó ń lù Ọ́?”
69 Lákòókò yìí, bí Pétérù ti ń jókòó ní ọgbà ìgbẹ́jọ́, ọmọbìnrin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Ìwọ wà pẹ̀lú Jésù ti Gálílì.”
70 Ṣùgbọ́n Pétérù ṣẹ̀ ní ojú gbogbo wọn pé “Èmi kò tilẹ̀ mọ ohun tí ẹ ń sọ nípa rẹ̀.”
71 Lẹ́yìn èyí, ní ìta lẹ́nu ọ̀nà, ọmọbìnrin mìíràn tún rí i, ó sì wí fún àwọn tí ó dúró yíká pé, “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jésù ti Násárẹ́tì.”
72 Pétérù sì tún ṣẹ́ lẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lú ìbúra pé, “Èmi kò tilẹ̀ mọ ọkùnrin náà rárá.”
73 Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó ń dúró níbi ìran yìí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, àwa mọ̀ ọ́. Èyí sì dá wa lójú nípa àmì ohùn rẹ̀ tí ó ń ti ẹnu rẹ jáde.”