42 Wọ́n kẹ́gàn Rẹ̀ pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀. Ìwọ ọba àwọn Ísírẹ̀lì? Sọ̀ kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsìn yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́.
43 Ó gba Ọlọ́run gbọ́, jẹ́ kí Ọlọ́run gbà á là ní ìsinsin yìí tí òun bá fẹ́ ẹ. Ǹjẹ́ òun kò wí pé, èmi ni Ọmọ Ọlọ́run?”
44 Bákan náà, àwọn olè tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Rẹ̀ fi í ṣe ẹlẹ́yà.
45 Láti wákàtí kẹfà ni òkùnkùn fi sú bo gbogbo ilẹ̀ títí dé wákàtí kẹsàn-án ọjọ́
46 Níwọ̀n wákàtí kẹsàn-án ní Jésù sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Èlí, Èlí, Làmá Sàbákitànì” (ní èdè Hébérù). Ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, è é ṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”
47 Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kò yé díẹ̀ nínú àwọn ẹni tí ń wòran, nígbà tíwọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, Wọ́n wí pé ọkùnrin yìí ń pe Èlíjà.
48 Lẹ́sẹ̀ kan náà, ọ̀kan nínú wọn sáré, ó mú kànrìkàn, ó tẹ̀ ẹ́ bọ inú ọtí kíkan. Ó fi lé orí ọ̀pá, ó gbé e sókè láti fi fún un mu.