43 Ó gba Ọlọ́run gbọ́, jẹ́ kí Ọlọ́run gbà á là ní ìsinsin yìí tí òun bá fẹ́ ẹ. Ǹjẹ́ òun kò wí pé, èmi ni Ọmọ Ọlọ́run?”
44 Bákan náà, àwọn olè tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Rẹ̀ fi í ṣe ẹlẹ́yà.
45 Láti wákàtí kẹfà ni òkùnkùn fi sú bo gbogbo ilẹ̀ títí dé wákàtí kẹsàn-án ọjọ́
46 Níwọ̀n wákàtí kẹsàn-án ní Jésù sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Èlí, Èlí, Làmá Sàbákitànì” (ní èdè Hébérù). Ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, è é ṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”
47 Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kò yé díẹ̀ nínú àwọn ẹni tí ń wòran, nígbà tíwọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, Wọ́n wí pé ọkùnrin yìí ń pe Èlíjà.
48 Lẹ́sẹ̀ kan náà, ọ̀kan nínú wọn sáré, ó mú kànrìkàn, ó tẹ̀ ẹ́ bọ inú ọtí kíkan. Ó fi lé orí ọ̀pá, ó gbé e sókè láti fi fún un mu.
49 Ṣùgbọ́n àwọn ìyókù wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a wò ó bóyá Èlíjà yóò sọ̀ kalẹ̀ láti gbà á là.”