47 Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kò yé díẹ̀ nínú àwọn ẹni tí ń wòran, nígbà tíwọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, Wọ́n wí pé ọkùnrin yìí ń pe Èlíjà.
48 Lẹ́sẹ̀ kan náà, ọ̀kan nínú wọn sáré, ó mú kànrìkàn, ó tẹ̀ ẹ́ bọ inú ọtí kíkan. Ó fi lé orí ọ̀pá, ó gbé e sókè láti fi fún un mu.
49 Ṣùgbọ́n àwọn ìyókù wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a wò ó bóyá Èlíjà yóò sọ̀ kalẹ̀ láti gbà á là.”
50 Nígbà tí Jésù sì kígbe ní ohùn rara lẹ́ẹ̀kan sí i, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀, ó sì kú.
51 Lójú kan náà aṣọ ìkélé tẹ̀ḿpìlì fàya, láti òkè dé ìsàlẹ̀. Ilẹ̀ sì mì tìtì. Àwọn àpáta sì sán.
52 Àwọn isà òkú sì sí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn olódodo ọkùnrin àti obìnrin tí ó ti kú sì tún jíǹde.
53 Wọ́n jáde wá láti isà òkú lẹ́yìn àjíǹde Jésù, wọ́n sì lọ sí ìlú mímọ́. Níbẹ̀ ni wọ́n ti fi ara han ọ̀pọ̀ ènìyàn.