6 Ṣùgbọ́n kò sí níhìn-ín. Nítorí pé ó ti jíǹde, gẹ́gẹ́ bí òun ti wí. Ẹ wọlé wá wo ibi ti wọ́n tẹ́ ẹ sí.
7 Nísinsìn yìí, Ẹ lọ kíákíá láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ pé, ‘Ó ti jíǹde kúrò nínú òkú. Àti pé òun ń lọ sí Gálílì síwájú yín, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóògbé rí i, wò ó, o ti sọ fún yin”.
8 Àwọn obìnrin náà sáré kúrò ní ibojì pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ayọ̀ ńlá. Wọ́n sáré láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn nípa ìróyìn tí ańgẹ́lì náà fi fún wọn.
9 Bí wọ́n ti ń sáré lọ lójijì Jésù pàdé wọn. Ó wí pé, “Àlàáfíà” Wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọ́n gbá a ní ẹṣẹ̀ mú. Wọ́n sì forí balẹ̀ fún un.
10 Nígbà náà, Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arákùnrin mi pé, ‘Kí wọ́n lọ tààrà sí Gálílì níbẹ̀ ni wọn yóò gbé rí mi.’ ”
11 Bí àwọn obìnrin náà sì ti ń lọ sí ìlú, díẹ̀ nínú àwọn olùṣọ́ tí wọ́n ti ń ṣọ́ ibojì lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.
12 Wọ́n sì pe ìpàdé àwọn àgbààgbà Júù. Wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn olùṣọ́.