5 Lẹ́yìn èyí ni èṣù gbé e lọ sí ìlú mímọ́ náà; ó gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹ̀ḿpìlì.
6 Ó wí pé, “Bí ìwọ̀ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, Bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ. A sa ti kọ̀wé rẹ̀ pé:“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ nítorí tìrẹwọn yóò sì gbé ọ sókè ni ọwọ́ wọnkí ìwọ kí ó má baà fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”
7 Jésù sì da lóhùn, “A sìáà ti kọ ọ́ pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”
8 Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo orílẹ̀-èdè ayé àti gbogbo ẹwà wọn hàn án.
9 Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.”
10 Jésù wí fún un pé, “Kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, ìwọ Sàtánì! Nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ ó sìn.’ ”
11 Nígbà náà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àwọn ańgẹ́lì sì tọ̀ ọ́ wá láti jísẹ́ fún un.