10 Nígbà tí Jésù gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Ísírẹ́lì tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí.
11 Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìha ìlà-oòrùn àti ìhà iwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Ábúráhámù àti Ísáákì àti Jákọ́bù jẹun ní ìjọba ọ̀run.
12 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọba ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.”
13 Nítorí náà Jésù sì wí fún balógun ọ̀run náà pé, “Máa lọ ilé, ohun tí ìwọ gbàgbọ́ ti rí bẹ́ẹ̀.” A sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ náà lára dá ní wákàtí kan náà.
14 Nígbà tí Jésù sì dé ilé Pétérù, ìyá ìyàwó Pétérù dùbúlẹ̀ àìsàn ibà.
15 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù fi ọwọ́ kan ọwọ́ rẹ̀, ibà náà fi í sílẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì dìde ó ń ṣe ìrànṣẹ fún wọn.
16 Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde. A sì mú gbogbo àwọn olókùnrùn láradá.